Canada real estate: Olóòtú Trudeau fẹ́ wọ́gilé kí àjòjì máa ra ilé ní ìlú wọn

Justin Trudeau

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olootu Canada Justin Trudeau ti gbe aba kan kalẹ láti gbegi le bi awọn ajoji ṣe n ra ile ni orílẹ̀èdè wọn fun ọdun meji si isinsiyi.

Idi ti wọn fi ṣe eyi ni pe wọn n gbiyanju lati yanju awọn iṣoro to ni ṣe pẹlu riri ile ti ko gun ni lapa gba lati gbe.

Owo ile ti fo soke ju ida ogún lọ eyi to ti fẹ́rẹẹ́ sun owo ile ni Canada si C$817,000 ($650,000; £495,000), eyi to jẹ ìlọ́po mẹsan iye ti awọn to n gbe ile naa n pa.

Ọgbẹni Trudeau ti ṣeleri lati moju to ọrọ bi ile yoo ṣe rọrun lati gba, o ṣe eyi lasiko to n ṣe ipolongo rẹ lọdun to kọja.

Ki ni erongba aba yii?

Toronto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Trudeau ṣagbekalẹ aba isuna yii l'Ọjọbọ ọ̀sẹ̀ to fi mọ gbigbegi le awọn ajoji to n ra ile. Aba naa fẹ gba ọpọlọpọ bilionu eeyan sẹgbẹ lati ro kíkọ́ awọn ile tuntun ati pe ki wọn le gbe awọn eto míì jade bíi nini apo àsùnwọ̀n owo ti wọn ko ni maa yọ owo ori lori wọn fún àwọn to ba ra ile wọn àkọ́kọ́.

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Ẹwẹ, ofin ti wọn gbe le awọn onrale lati orileede míì ko ni pa awọn olugbe to jẹ pe ibẹ ni wọn ti n gbe fun ọjọ pipẹ, awọn akẹ́kọ̀ọ́ to wa latokere àtàwọn oṣiṣẹ to fi mọ awọn to ba n ra ile ti wọn diidi fẹ maa gbe.

Ki làwọn onímọ̀ nipa rira ile sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí?

Awọn to mọ daadaa nípa ile rira lagbo katakara ilé ni ko ye awọn boya gbigbẹsẹ ofin le awọn ajoji to fẹ ra ile ni yoo yanju isoro to wa nilẹ yìí.

Ọrọ lori iye awọn ajoji to n ra ile si Canada, wọn ni ko pọ, àmọ́ iwadii fihan pe awọn to nkan ranpẹ kan lagbo katakara ile.

Ben Myers to jẹ Ààrẹ Ileeṣẹ olugbaninimọran lori èyí, Bullpenn Research &Consulting in Toronto wadii sita pe ida ẹyọkan pere ni awọn ajoji to ra ile lọdun 2020 eyi to si dinku kuro ni ida mẹsan lọdun 2015 si 2016.

Ọgbẹni Myers "mi o ro pe o ma ni ipa rẹpẹtẹ. Awọn to fi bẹẹ fẹ ra ile yoo wa ọna ti wọn yoo gba ṣe e".

Ó ní tori iye eeyan to pọ sii lọ da kun ọ̀wọ́ngógó ilé ati adinku to ba rírí ile gba.

Àkọlé fídíò, Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

Iroyin ni ọrọ naa buru jai sii lati asiko ajakalẹ arun Covid-19 lọdun 2020 nigba ti awọn aṣepinnu ni Canada ja iye ere orí owó walẹ ki ọrọ aje le ba ara mu.

Ìpinnu aato naa mu adinku ba àti rí owo yà eyi to mu ki wiwa ile pọ sii.

Gẹgẹ bi àkọsílẹ̀, iye alafo to wa laarin owo ile ati owo ti olugbe Canada n rí jẹ eyi to ya ni lẹ́nu ju.