Canada: Wo iye iàsìkò tí yóò ná ọ láti dé Canada

Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sáré wọ inú ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, @laffbro, Getty images

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sáré wọ inú ọkọ̀

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria to le ni igba ẹgbẹrun lo ti ya soju opo Twitter wọn lati ọjọ abamẹta ti ajọ INEC sun ọjọ idibo Naijiria siwaju ti wọn si n ke tantan pe orilẹede Canada lo ku ti awọn yoo mori le.

Eyi wa lara ọna ti awọn ọmọ Naijiria n gba fi ẹhonu han lẹyin ti wọn ji lowurọ kutu hai lati lọ dibo ti wọn wa ṣaa dede gbọ pe ajọ eleto idibo ti sun idibo siwaju lọjọ idibo gangan iyẹn lati ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji lọ si ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun 2019.

Awọn ọmọ Naijiria ọhun to n fi ibinu wọn han n sọ pe, niwọn igba ti ajọ INEC ti jawọn kulẹ, awọn yoo fi Naijiria silẹ lọ si Canada.

Amọ ṣaa, yẹyẹ ni ọpọ fi ọrọ naa ṣe.

Nitori naa, latari ariwo "Canada ya" t ogbode kan, ẹ wo alaye kikun nipa iye akoko ti yoo naa ẹni to ba fẹ rawọle irinajo yii nipa ibeere ati idahun to wa nisalẹ.

Ti o ba rin

  • Yoo gba ọ to 2 months ati 1 week lati rin lati Lagos de Toronto (Canada)
  • Yoo gba ọ to 3 months ati 4 weeks lati rin lati Lagos de Syndey (Australia)
  • Yoo gba ọ to 2 months ati 1 week lati rin lati Lagos de New York (US)
  • Yoo gba ọ to 1 month ati 2 weeks lati rin lati Lagos de London (UK)
  • Yoo gba ọ to 3 months lati rin lati Lagos de Beijing (China)
  • Yoo gba ọ to 1 month ati 2 weeks lati rin lati Lagos de Berlin (Germany)


Ti o ba wọ ọkọ

  • Yoo gba ọ to 3 days ati 21 hours ti o ba wọ bọọsi lati Lagos de Toronto (Canada)
  • Yoo gba ọ to 6 days ati 16 hours ti o ba wọ bọọsi lati Lagos de Syndey (Australia)
  • Yoo gba ọ to 3 days ati 16 hours ti o ba wọ bọọsi lati Lagos de New York (US)
  • Yoo gba ọ to 2 days ati 8 hours ti o ba wọ bọọsi lati Lagos de Beijing (China)
  • Yoo gba ọ to 5 days ati 7 hours ti o ba wọ bọọsi lati Lagos de London (UK)
  • Yoo gba ọ to 2 days ati 10 hours ti o ba wọ bọọsi lati Lagos de Berlin (Germany)


Ti o ba wọ baalu

  • Yoo gba ọ to 11 hours ati 19 minutes ti o ba wọ baalu lati Lagos de Toronto (Canada)
  • Yoo gba ọ to 19 hours ati 26 minutes ti o ba wọ baalu lati Lagos de Syndey (Australia)
  • Yoo gba ọ to 10 hours ati 41 minutes ti o ba wọ baalu lati Lagos de New York (US)
  • Yoo gba ọ to 6 hours ati 46 minutes ti o ba wọ baalu lati Lagos de London (UK)
  • Yoo gba ọ to 15 hours ati 28 minutes ti o ba wọ baalu lati Lagos de Beijing (China)
  • Yoo gba ọ to 7 hours ati 1 minute ti o ba wọ baalu lati Lagos de Berlin (Germany)