#NigeriaDecides2019: Mo rọ àwọn ọmọ Nàíjíríà láti máṣe fa ìjàngbọ̀n

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fi ika hanu lori bi ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, se sun eto idibo aarẹ to yẹ ko waye lọjọ abamẹta siwaju.

Ninu atẹjade kan to fi sita, Buhari ni ijakulẹ nla ni oun ba pade lati ọdọ ajọ INEC naa, lai naani ọjọ gbọọrọ ti wọn ni lati palẹmọ fun idibo ọhun, ati bawọn ọmọ Naijiria ati oke okun se n gbaradi fun idibo naa.

Buhari ni, ọpọ ọmọ Naijiria lo rin irin ajo lọ si orisirisi agbegbe lati di ibo wọn, tawọn onwoye lati oke okun si ti gbaradi lati wo bi ibo naa yoo se lọ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe, ajọ INEC funra rẹ gan ti n fi ọwọ idaniloju sọya lojoojumọ pe didun ni ọsan yoo so nidi ibo naa, ti wọn si n kede igbaradi wọn pe ohun gbogbo ti wa ni sẹpẹ, ti ọpọ eeyan si gba wọn gbọ.

Aarẹ orilẹ ede yii tun sọ siwaju pe ijọba oun ti seleri saaju pe, ko ni tọwọ bọ eto idibo naa loju tabi isẹ ajọ INEC, yatọ si pe oun gbe owo kalẹ fun wọn.

Àkọlé fídíò, Àwọn ará Ìpínlẹ̀ Oyo ní ìgbésè INEC lọrí ìdìbò kù díẹ̀ káàtó

Buhari wa n rọ ajọ eleto idibo ilẹ wa naa, lati ri daju pe, gbogbo awọn ohun eelo idibo ti wọn ti pin kaakiri ni aabo to gbopọn wa fun, ti ko si bọ si ọwọ awọn eeyan ti ko yẹ.

Bakan naa lo tun rọ ajọ Inec lati yanju awọn kudiẹ-kudiẹ to waye, ti wọn fi sun ibo ọhun siwaju, bẹẹ si tun ni ko ri daju pe idibo ti yoo se ko ni ẹja n bakan ninu.

O tun rọ awọn ọmọ Naijiria lati takete si iwa jagidi-jagan, amọ ki wọn gba alaafia laaye, ki ohunkohun ma baa pagidina eto isejọba alagbada wa.

Inec sun ibo aarẹ siwaju, PDP, APC fariga

Awọn ẹka olupolongo fún ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni inu awọn ko dùn si bi INEC ṣe sún ididbo siwaju.

Festus Keyamo to jẹ oludari ajọ olupolongo fun gbigbe Buhari wọle lẹẹkeji lo buwọlu atẹjade naa.

O ni ohun ti ajọ eleto idibo INEC ṣe yii ku diẹ kaato.

bbc kaadi
Àkọlé àwòrán, Idibo ko ni waye mọ loni, ọpọ n fero wọn han

Bẹẹ, o menuba awọn ohun ti ajọ eleto idibo INEC beere ni eyi ti ijọba apapọ yti pese fun wọn ṣaaju oni ọjọ idibo.

Festus Keyamo fẹsun kan awọn ẹgbẹ oṣelu alatako, iyẹn People's Democratic Partty pé kò ṣeyin wọn.

Yakub
Àkọlé àwòrán, Ojogbon Mahmood Yakubu kede sisun idibo siwaju pe INEC ko tii pari iṣẹ lori eto

Egbẹ oṣelu PDP naa bẹnu ẹ̀tẹ́ lu bi ajọ eleto idibo INEC ṣe sun eto idibo naa siwaju pé ko tẹ awọn lorun.

Uche Secondus to jẹ alaga ifitonileti fun ẹgbẹ alatako PDP ni inu ẹgbẹ ko dun rara si igbese ajọ INEC yii.

Bayii, PDP ti pè fún ikọwefiposilẹ alaga ajọ INEC pe ko maa lọ sile.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: kò yé kí ìdájọ́ òfin yàtó síra wọn ni Naijiria

Ojọgbọn Mahmood Yakubu ni alaga ajọ eleto idibo to ṣe ikede yii loru nibi ipade pajawiri ti ajọ INEc ṣe lafẹmoju ọjọ idibo.

O ni wọn yoo dibo aarẹ ati ti awọn ọmọ ilé igbimọ aṣofin lọjọ́ kẹtalelogun, osù keji àti ti gomina sí ọjọ́ kẹsan an, oṣù kẹta, ọdun 2019 nigba ti ajọ naa ba ti yanju eto wọn to mẹhẹ.

Ọpọlọpọ ara ilu lo n binu pe asiko ti ajọ INEC fi sun idibo yii siwaju kere nitori kii ṣe wakati diẹ si eto idibo lo yẹ ki wọn maa ṣe iru ikede yii.

Àkọlé fídíò, #NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí