Rwanda Genocide: 'Mo dáríji ẹni tó pa mí lọ́kọ́, mò sì gbà kí àwọn ọmọ wa fẹ́ ara wọn'

Ifẹ nikan lo le wo ọgbẹ ọkan san.
Eyi ni esi ti arabinrin, ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, ma n sọ fun awọn eeyan, nipa bo sẹ dariji ọkunrin to pa ọkọ rẹ, to si tun gba ki ọmọ wọn fẹ ara wọn.
Ọdun 1994 ni ọkọ Bernadette Mukakabera ku lasiko ti ipaniyan waye ni orilẹ-ede Rwanda, nibi ti eeyan bi ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin, 800,000 ku laarin ọgọrun ọjọ pere.
Arabinrin Bernadette sọ fun BBC pe oun gba ki ọmọ ẹni to pa ọkọ oun, fẹ ọmọ oun lọkọ, nitori pe awọn ọmọ naa ko ni nkankan ṣe e nipa iṣẹlẹ ọhun.
"Ko si ohunkohun to yẹ ko di eeyan lọwọ lati fi ifẹ han si ara wọn."
Ọmọ ẹya Tutsi ni Bernadette ati ọkọ rẹ, Kabera Vedaste, nibi ti awọn kan ti fi ibọn já baalu to gbe aarẹ Rwanda nigba naa, lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 1994.
Laarin wakati perete, ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan ẹya Hutu, bẹrẹ si i pa awọn eeyan Tutsi jakejado orilẹ-ede wọn.
Eyi ko ṣẹyin ikorira to ti wa nilẹ fun ọpọ ọdun.
Lara awọn eeyan yii ni Gratien Nyaminani, ti idile rẹ n gbe ni ẹgbẹ ile Bernadette nilu Mushaka.
Oun si lo pa ọkọ arabinrin naa.
Lẹyin ipaniyan yii ni ikọ ọlọtẹ lati ẹya Tutsi, gbajọba. Wọn si fi ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ti wọn fi ẹsun ipaniyan kan, si ahamọ.
Wọn mu Gratien Nyaminani naa, o si koju igbẹjọ nile ẹjọ ibilẹ kan.

Oríṣun àwòrán, AFP
Nibi igbẹjọ naa to n waye ni ọsọọsẹ, ni awọn ti wọn fi ẹsun kan, ti n pade awọn araalu, lati sọ bi wọn ṣe pa awọn ti wọn pa.
Lọdun 2004, Ọgbẹni Gratien sọ fun Bernaditte nibi igbẹjọ, bo sẹ pa ọkọ rẹ.
O bẹẹ fun iwa rẹ. Nibẹ si ni arabinrin naa ti sọ pe oun darijin.
Idariji naa si ni ko jẹ ki wọn o dajọ ẹwọn ọdun mọkandinlogun to yẹ ko lọ. Dipo bẹẹ, o ṣiṣẹ sin ilu fun ọdun meji.
Laarin ọdun mẹwaa to fi wa ni ahamọ ṣaaju idajọ, ẹbi gratien gbiyanju lati ṣe atunṣe lọdọ Bernaditte ati ọmọ rẹ, alfred, to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla nigba ti baba rẹ ku.
Lasiko naa ni ọmbinrin Gratien, Yankurije Sonata, naa ma n lọ si ile arabinrin naa, lati ba a ṣe iṣẹ ile.
Ọmọ ọdun mẹsan-an ni lasiko ti ipaniyan naa waye.

O sọ fun BBC pe oun ma n ran obinrin naa lọwọ, nitori pe ko ni oluranlọwọ lẹyin ti baba oun pa ọkọ rẹ.
"Asiko naa ni mo lero pe Alfred bẹrẹ si ni ifẹ mi, bi mo ṣe n ran iya rẹ lọwọ."
Alfred wa ni ile ẹkọ nigba naa.
Bernaditte sọ pe oun ko lodi si pe ki ọmọ oun fẹ ẹ, nitori pe oun nifẹ ọmọbinrin naa.
Ṣugbọn nigba ti wọn sọ ọrọ igbeyawo naa fun Gratien, ẹru ba a, o si jẹ iyalẹnu pe ẹbi to pa lẹkun le gba ki ọmọ oun fẹ ọmọ wọn.

Amọ nigba ti Bernadette ṣalaye fun pe oun ko ni erongba lati ṣe ọmọ rẹ ni ijamba to ba di iyawo ọmọ oun, nitori nkan ti baba rẹ ṣe, ọkan rẹ balẹ.
Tọkọtaya naa ṣe igbeyawo wọn lọdun 2008, ninu ile ijọsin Katoliki ilu naa.
Ninu ile ijọsin naa ni Gratien ti tọrọ aforiji lọdun meji ṣaaju igbeyawo wọn.








