Nigeria Army: Ọmọ ogún Nàìjíríà tó n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ISWAP ṣekú pa ará rẹ̀ lẹyìn tí àṣírí tú

Oju ogun awọn ologun Naijiria pẹlu awọn ọmọ agbebọn ISWAP

Oríṣun àwòrán, Hq nigeria army

Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe ọmọ ogun Naijiria kan ti ṣeku pa ara rẹ lẹyin ti awọn alaṣẹ mu lori ẹsun pe o n lẹdi apo pọ pẹlu awọn agbesunmọmi ISWAP.

Awọn to sunmọ ileeṣẹ ologun Naijiria ṣalaye pe niṣe ni arakunrin ọmọ ogun yi n bawọn alaburu yi kopa ninu awọn ikọlu ti wọn ṣe si awọn ileto kan ni ipinlẹ Yobe laipẹ.

Èyí mú kí lawọn ologun bẹrẹ si ni fura si pe ọwọ rẹ ko mọ lẹyin ikọlu kan to ṣẹlẹ si agbegbe Geidam ati Gashua.

Ko pẹ si igba naa ni wọn ba mu lẹyin ti asiri tu pe oun ati awọn agbesunmọmi yi jijọ n lẹdi apo pọ.

A gbọ pe ọmọ ogun yi to mọ nipa lilo nkan ija oloro yọ boro mọ awọn to mu lọwọ to si ja ibọn gba lọwọ eeyan kan ninu awọn to mu.

Ka to ṣẹju pẹrẹ, ibọn to gba yi la gbọ pe o fi pa ara rẹ tohun ti pe wọn de ọwọ rẹ.

O ti to ọjọ mẹta tawọn to n woye eto aabo Naijiria ti n fura si pe awọn ọmọ ogun kan n lẹdi apo pọ pẹlu awọn agbesunmọmi.

Iru iwà bayi si mu ki o ṣoro diẹ lati rẹyin awọn alaburu yi.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

O ti le ni ọdun mẹwaa ti ikọ agbesunmọmi Boko Haram ati ikọ ISWAP to ya kuro lara wọn ti n ṣe ikọlu si awọn ọmọ ogun orileede Naijiria.

Lọsẹ to kọja ikọ awọn agbesunmọmi yi pa o kere tan eeyan mẹwaa ti awọn aimọye eeyan mi si farapa ni ile ọti igbafẹ kan ni ilu Geidam lẹba ibode Naijiria ati Niger.

Ninu awọn to ba isẹlẹ yi lọ lawọn obinrin wa taa si gbọ pe wọn yinbọn pa wọn ti wọn tun de ọwọ awọn eeyan miran ki wọn to dunbu wọn bi ẹran.

Iṣẹlẹ yi waye ni aipẹ si igba tawọn eeyan mọkandinlogun kan farapa tawọn mẹfaa si ku ninu ibugbamu ado oloro kan to waye ni ipinlẹ Taraba.

Ikọ ISWAP kede pe isẹ ọwọ awọn ni ikọlu yi jẹ.