Amotekun: Akeredolu àti PDP tahùn síra wọn lórì owó oṣù òṣìṣẹ́ l'Ondo

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ondo ti fẹsun kan ijọba ipinlẹ naa pe o n mura lati yọ lara owo oṣu awọn oṣiṣẹ lati fi gbọ bukata ikọ alaabo Amotekun.

PDP ni o jẹ ohun ti ko ṣee gbọ seti pe ebi n pa awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo lasiko ti awọn ẹgbẹ lawọn ipinlẹ mii n gbadun ijọba wọn.

Ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ ni agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Kennedy Peretei ti fi ọrọ naa lede.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo wa lara awọn ti oju n pọn julọ ni Naijiria.

O ni igbesẹ naa ko ṣẹyin bi awọn ṣe n kan sara si gomina Rotimi Akeredolu lori iṣẹ takun-takun ti ikọ Amotekun n ṣe l'Ondo lati koju awọn ọdaran Fulani darandaran.

Peretei sọ pe "Lẹta kan ti wọn tẹ jade nipa iye ti wọn yoo maa yọ ninu owo oṣu awọn oṣiṣẹ to wa ni oniruru ipele fi han pe gomina to wa lori alefa lọwọ yii ko kọbi ara si iya ti awọn eeyan ipinlẹ Ondo n jẹ."

"Ṣe ka sọ pe gomina ko ni owo ti yoo ya sọtọ si ẹka Amotekun ni abi ka kuku sọ pe o kan n wa ọna lati ko owo ilu sapo?"

"Bawo ni gomina ṣe n na owo ti ijọba apapọ fi ranṣẹ si loṣoṣu gẹgẹ bii owo ti wọn la kalẹ fun eto abo?

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso

"Abi ka kuku sọ pe awọn amugbalẹgbẹ rẹ lo n ṣi lọna lati tọwọ bọ owo oṣu awọn oṣiṣẹ?"

Peretei wa rọ Akeredolu lati tu ero rẹ pa, ko si bojuto bi yoo ṣe maa na owo ipinlẹ Ondo ki awọn oṣiṣẹ rẹ le kuro ninu oṣi.

Akeredolu fesi pada

Ẹwẹ, agbẹnusọ Akeredolu, Richard Olatunde ti sọ pe irọ to jina si ootọ ni atẹjade ẹgbẹ oṣelu PDP lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ, Olatunde ni ẹgbẹ oṣelu PDP kan n mọọmọ parọ fun awọ araalu lati ba orukọ ijọba Akaeredolu jẹ ni.

O ni "Gẹgẹ bii ọpọ eeyan ṣe mọ, onirọ ni PDP, iṣe wọn si ni lati maa pa irọ fun awọn araalu."

"Ijọba ipinlẹ Ondo ko ni erongba kankan lati yọ lara owo oṣu awọn eeyan ipinlẹ yii."

Lẹyin naa lo pe PDP nija lati mu lẹta ti wọn n sọ nipa rẹ jade, ninu eyii ti wọn ti ni ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe oun yoo yọ lara owo oṣu awọn oṣiṣẹ.

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...