ASUU Strike: Ẹ má torí ìyansẹ́lódì ASUU dá ètò òṣèlú rú- Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà sì ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ NANS

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Olori ile asofin agba Naijiria Sẹnẹtọ Ahmad Lawan ti parọwa si awọn akẹkọọ orileede naa lti ma se da eto oselu ru.
Lawan fi ẹbẹ yi sita lasiko ti aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ Sunday Ashefon ati awọn ikọ igbimọ alasẹ rẹ sabẹwo si aarẹ ile asofin agba.
Bisọọbu ijọ Methodist,Sunday Onuoha lo lewaju ikọ awọn akẹkọọ yi si ọdọ aarẹ ile asofin agba.
- Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe Poly ní Nàìjíríà , ASUP bẹ́rẹ́ ìyanṣẹ́lódì, wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ ní Makinde gbà tíkẹ̀ẹ̀tì Sẹ́nétọ̀ lọ́wọ́ Kola Balogun fún Joseph Tegbe?
- Buhari pàṣẹ fún àwọn mínísítà tó bá fẹ́ dupò òṣèlú láti kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní kíá
- Genevieve Nnaji fi fídíò sí Instagram, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìròyìn sọ pé ó ní àrùn ọpọlọ
- Johnson Sulemann sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn tí Stephanie Otobo fi kàn án
- Buhari kò ní fi oṣù mẹ́fà kún ìjọba rẹ̀ bí àwọn kan ṣe ń bèrè - Ìjọba àpapọ̀̀̀
- Wo àwọn tó ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Ṣé lóòtọ́ ni Jonathan ti gbẹ̀yìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC? Nkan tí PDP àti APC sọ rèé
- Wo ìdí tí Ilé aṣòfin àpàpọ̀ Nàìjíríà ṣe yí òfin ìdìbò padà fún ààrẹ, gómìnà, àwọn aṣòfin àtàwọn míràn
- Kò sí akẹ́kọ̀ọ́ ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara tí yóò ṣe ìdánwò WASSCE lọ́dún 2022
- Ìdí mẹ́ta tí Goodluck Jonathan kò fi lè díje dupò lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan lásìkò yìí
- Wo àwọn obìnrin mẹ́wàá tí ipa wọn kò ṣe fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní ààfin Oyo
Ebẹ ti Lawan n bẹ awọn akẹkọọ yi ko sẹyin bawọn akẹkọọ́\se ni ara ko ni rọ okun ko ni rọ adiẹ lopin igba tawọn ile ẹkọ fasiti ba wa ni titi pa.
Lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria, awọn akẹkọọ ti n kora jọ ti wọn si n leri pe awọn yoo gbe igbesẹ lati ri pe gbogbo eto oselu ko ni waye ayafi ti ijọba ba wa ojutu si aawọ iyansẹlodi pẹlu awọn ẹgbẹ olukọ fasiti Naijiria,ASUU.
Nigba to n fesi pada si ọrọ ileri awọn akẹkọọ yi, aarẹ ile asofin agba Naijiria sọ pe ki awọn akẹkọọ yi jọwọ ma se yẹ kuro loju ọna ijiroro to n lọ lọwọ lati pẹtu saawọ yi.
Lawan sọ pe , "Mo fẹ mu amọran wa, mi o lero pe yoo tọ ki ẹ da eto oselu ru.Ko yẹ ki a se bẹ, mi o si lero pe a nilo lati se bẹ''
"Nkan taa ni lati se ni pe ki a si maa tọ oju ọna ijiroro ka si yago fun ikọlu kankan.Nigba taa ba tẹnu mọ ijiroro ni yoo rọrun fun wa lati ri nkan taa sagbega le lori.''
Bakan naa ni Lawan sọ pe ile asofin agba n gbiyanju lati ri pe iyansẹlodi awọn olukọ fasiti yi jẹ nkan to wa
O fi kun pe''ohun tẹ fẹ ni ki ijọba apapọ ati ẹgbẹ ASUU pada si ibi ijiroro.A ti gbọ ibeere yin yi.A ti buwọlu a o si gbe igbesẹ le lori ni kiakia''
"Anfaani leleyi jẹ fun wa lati parọwa si ẹgbẹ ASUU lati dawọ iyansẹlodi yi duro nitori ko si bi wọn yoo se ribi jiroro pẹ́lu ijọba bi wọn ko ba si lẹnu isẹ.Anfaani leleyi jẹ fun wa lati ri wọn, ki a si si ọna silẹ ki wọn so iyansẹlodi rọ fun igba diẹ ka si ri ibi taa ba ọrọ yi de'
O se diẹ tawọn akẹkọọ fasiti ti wa nile
Laipẹ yi ni ipade kan to yẹ ko wa ojutu si aawọ iyansẹ́lodi awọn akẹkọọ fasiti ati ijọba tun fori sanpọn.
Ni kukuru awọn akẹkọọ yoo tun wa ni ile fun osu mejila nitori airojutu aawọ yi laarin ijọba ati ẹgbẹ olukọ fasiti.
Lati ọjọ kẹrinla osu Keji ọdun yi ni iyansẹlodi naa ti bẹrẹ.
Asuu tẹnumọ pe ijọba ni ko fẹ yanju ọrọ yi pẹlu bi wọn ko se sika adehun ọdun 2019 ti wọn se pẹlu awọn.
Wahala airi ọrọ yi yanju lo mu kawọn akẹkọọ to ti wa nile ti ọpọ ko si ri nkankan se se sọ pe awọn ko ni jẹ ki ijọba naa ri ẹdọ fi lori oroonro bi wọn ko ba da awọn pada si kilaasi.
Ni nkan bi wakati meloo kan sẹyin lawọn ẹgbẹ osisẹ Naijiria naa sọ pe awọn yoo darapọ mọ awọn olukọ fasiti nibi iyansẹlodi bi ijọba ko ba yanju ọrọ yi laarin ọjọ mẹsan.
















