AMVCA 2022: Bí àmì èye AMVCA ti odún yìí yóò se lo nìyíí

AMVCA

Oríṣun àwòrán, @africamagictv

Gbogbo eto lo ti to fun ayẹyẹ gbigba ami ẹyẹ Ilẹ Africa ti ''Africa Magic Viewers'Choice Awards (AMVCA), ti yoo waye ni Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Karun un.

Ami ẹyẹ naa ni awọn kan ma n pe ni ami ẹyẹ ti Oscar ti ilẹ Afrika, ti wọn ti n fun awọn oṣere fiimu, awọn to n gbe wọn jade ati awọn onimọ miran ni ẹka wọn.

Ọdun yii ni ami ẹyẹ naa tun pada si ilẹ Afrika lẹyin ti wọn ko lee ṣe ni ọdun to kọja nitori ajakalẹ aarun Coronavirus.

Awọn alakoso ami ẹyẹ naa ti kede pe igun mẹtalelọgbọn ni wọn pin ami ẹyẹ naa si ti mejila nin

u wọn yoo si fun awọn eniyan ni anfaani lati di ibo.

Miliọnu kan naira ni ẹni ti awo orin rẹ pegede julọ yoo gba.

Gbajugbaja onifiimu, Victor Okhai ni yoo ṣe akoso awọn ti yoo kede ẹni to bori, ti wọn yoo si fun ni alami ẹyẹ naa.

Ni saa yii, wọn ti ṣafikun ami ẹyẹ fun ẹni to n pegede julọ lori ẹrọ ayelujara (Best Online Social Content Creator.)

Awọn ti yoo dije dupo naa ni awọn adẹrinpoṣonu bii Mr. Macaroni, Taaooma, Tee Kuro, Elozonam, Oga Sabinus ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Mothers day: Lẹ́yìn Olorun, Ìyá mi ló kù- Papa Ajasco, Abiodun Ayeyinka

Tani yoo ṣakoso red carpet lasiko ami ẹyẹ naa?

Awọn alakoso ami ẹyẹ naa ni Toke Makinwa, Ebuka Obi-Uchendu, Uti Nwachukwu ati Sika Osei ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn eniyan mẹrin yii ni yoo ma a fi ọrọ wa awọn eniyan lẹnu wo lasiko ami ẹyẹ naa, ti wọn yoo si ba ṣafihan bi awọn eniyan ṣe mura si wa si ibi ayẹyẹ naa.

Awọn wo ni yoo wa lati Hollywood?

Awọn alakoso ami ẹyẹ AMVCA ti ni awọn oṣere lati Ilẹ Amẹrika,Hollywood.

Lara wọn ni Tasha Smith to kọpa ribiribi ninu fiimu 'Why Did I Get Married?' ati 'Why Did I Get Married, Too?'.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Arakunrin Bayo Akinfemi to kopa ninu fiimu ''Bob Hearts Abishola'' naa yoo darapọ mọ wọn.

Brandon Michael Hall naa to wa lara awọn to ṣe fiimu ''God, friended me'' naa yoo kopa.

To fi mọ Sidra Smith ati Grant Housley lati ileeṣẹ Hollywood ni ilẹ Amerika.

Bakan naa ni wọn yoo ṣepade pọ pẹlu awọn ogbongẹ ti wọn ti yan fun ami ẹyẹ AMVCA naa.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Akoko ti wọn yoo ṣafihan rẹ ni yii...

Awọn ti yoo wo ami ẹyẹ naa ni ori ẹrọ tẹlifisọn yoo wo o lori ẹrọ gbogbo Africa Magic ati Gotv.

Bakan naa ni wọn yoo ni anfani lati wo lori DSTV App ti wọn ba ni ẹrọ ayarabiasa to muna doko.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?

Awọn ẹka ti yoo gba Ami ẹyẹ naa ni;

  • Best Actress in A Comedy
  • Best Actor in A Comedy
  • Best Supporting Actress
  • Best Supporting Actor
  • Best Actress in A Drama
  • Best Actor in A Drama
  • Best Short Film or Online Video
  • Best Indigenous Language - Yoruba
  • Best Indigenous Language - Hausa
  • Best Indigenous Language - Igbo
  • Best Indigenous Language - Swahili
  • Best Art Director
  • Best Costume Designer
  • Best Lighting Designer
  • Best Picture Editor
  • Best Sound Editor
  • Best Sound Track
  • Best Make Up
  • Best Writer
  • Best Cinematographer
  • Best Movie Southern Africa
  • Best Movie East Africa
  • Best Movie West Africa
  • Best Overall Movie
  • Best Television Series
  • Best Director
  • Best Documentary
  • Best Africa Magic Original Drama Series
  • Best Africa Magic Original Comedy Series