Oladapo Okanlawon crippled Ibadan Embroider: Mo ń rìn dí ọmọ ọdún márùn-ún, atẹ́gùn kan ni wọ́n ló fẹ́ lù mí
"Mo maa n sọ fawọn eeyan pe mi o ki n ṣe onibara nigbakuugba ti wọn ba n na owo si mi".
Shonde Oladipupo gba BBC Yoruba lalejo nibi to ti n ṣe iṣẹ ọwọ rẹ eyi to fi n tọ iyawo ati ọmọ mẹta.
Onipenija ara ni Oladipupo amọ ko fi oju yi wo ara rẹ gẹgẹ bo ṣe ni oun kii gba ọjẹgẹ rara ko si ki n kaarẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo rẹ, Shonde ṣalaye bi o ṣe dede yi biri to di ẹni to rọ lẹsẹ mejeeji nigba to wa lọmọ ọdun marun.
"Mo n fi ẹsẹ mi rin titi di ọmọ ọdun marun, emi atawọn ẹgbẹ mi n ṣere ni ita ni atẹgun dede fẹ lu mi, awọn obi mi lo sọ fun mi".
O ṣalaye bi o ṣe pẹ ko to ri ọrẹ ba ṣere. O ka iwe mẹfa to si ni ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ lo ti n kọ iṣẹ fifi abẹrẹ ati ọwọ lasan ko iṣẹ Jakon si ara aṣọ.
O ṣalaye pe iṣẹ oun n lọ deede toripe ọwọ loun fi n ṣiṣẹ kii ṣe ẹsẹ to n dun oun.
Shonde ni igboya gidi ninu iṣẹ rẹ ti ko si jẹ ki ipenija rẹ di i lọwọọ pipese fun idile rẹ.

"Bi awọn eeyan ba bi mi pe arakunrin ṣe o n tọrọ agbe ni, mo maa n da wọn lohun pe rara, ẹyin ni tẹẹ ba ni ọmọ to fẹ kọ iṣẹ kẹẹ muu wa".
Ọlọrun fi iyawo ati ọmọ mẹta ta Shonde lọrẹ.
'Ọjọ́ méjì àti wákàtí díẹ̀ péré la fún Ramon Adedoyin láti gbé ìwée 'a kò ní ẹjọ́ jẹ́' wá sílé ẹjọ́'


