Blind Couple: Samson ati Temitope Oladele: Níbi ìdíje Akàndá ẹ̀dá ni a ti kọ́kọ́ padè kí a tó ṣe ìgbéyàwó

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Báyìí kọ́ ní wọ́n ṣe bí èmí àti aya mi ṣùgbọ́n a kọ̀ láti tọrọ bárà- Tokotaya to ni ipenija oju

Tokotaya Samson ati Temitope Oladele gba BBC Yoruba ni alejo ni ile wọn

Awọn mejeeji sọ nipa irinajo wọn lati ibẹrẹ ti wọn riran daadaa ki oju wọn to fọ bi wọn ṣe n dagba.

Samson to jẹ olorin ati Ojise Olorun ni pe awọn Obi koowa gbiyanju titi ṣugbọn ko si ọna abayọ ni.

Samson ati Temitope salaye lori bi wọn ṣe n la ipenija oju yii kọja ati awon iṣẹ bii ọṣẹ ṣiṣe ti won tun n ṣe ki wọn ma baa di alagbe.

Awọn mejeeji gba ẹni to je akanda ẹda ni imọran pe ki wọn lo ọpọlọ wọn bi o ti yẹ lai maa tọrọ bara, ki wọn si gbagbọ ninu Olorun

Afoju

Ko rọrun lati ni ọmọ afọju paapaa ti oju rẹ ko fọ lati ibẹ\re ṣugbọn a n gbiyanju agbara wa gẹgẹ bii Obi- Victoria Ojedokun.

Iya Temitope Oladele to jẹ iyawo Samson naa ba BBC Yoruba soro lori bi oun ṣe gba kadara ti oun si n sa ipa rẹ lori wọn.

Ibeji Oladele

Kini Olorun ko le ṣe?

Oyun to wa ninu Temitope Oladele lasiko ti BBC n ṣe ifọrọwanilẹnuwo yii lo ti fi bi ibeji lantilanti bayii.

Bi nkan ko daa, Olorun ko ni ṣe ne ni igbagbọ mi- Victoria Ojedokun.