Borno student slits 11-year-old's throat:Ọmọ kíláàsì àgbà fi bíléèdì gé gògòńgò ọmọ kíláàsì wẹ́wẹ́, àlàyé rèé

Jubril

Oríṣun àwòrán, Pr Nigeria

Àkọlé àwòrán, Wani hoto da BBC ta samu daga kafar PR Nigeria ya nuna aikin da aka yi wa yaron a asibiti a wuyansa

Iroyin taa tún ń gbọ́ to waye ni ilu Maiduguri ni pe ọmọ ile ẹ̀kọ́ girama kan fi bileedi gé gogongo ọmọ ile ẹ̀kọ́ rẹ kan naa to wa ni ipele àwọn ọmọde.

Iroyin ni torí Jubril Mato to jẹ ọmọ to wa ni ipele awọn to kere kọ láti jẹ isẹ ti eyi to wa ni ipele SS2 rán an.

Nibayii, Jubril wa ni ile iwosan Fasiti Maiduguri ni ẹ̀ka fún itọju ohun to burú jai látàrí pé ọmọ ile ẹ̀kọ́ àgbà náà dá seria fún un torí o kọ láti jiṣe fún un.

Iroyin ni "lalẹ ọjọ ti iṣẹlẹ yìí wáyé, ọmọ ile ẹ̀kọ́ ipele àgbà ohun wá mú Jubril lọ si ibi tó dakẹ rọrọ kan níbi tó ti lo bileedi fi gé ọrun rẹ lọpọlọpọ ọna leyi to jẹ ko fara pa de ibi awọn ẹ̀yà ara inu ọrun to fi mọ gogongo àti iṣan". Èèyàn kan to mọ nípa iṣẹlẹ ohun sọ fawọn oniroyin.

Eeyan to ri ohun tó sẹlẹ yìí ti awọn alasẹ ilé ẹ̀kọ́ kò fẹ sọ orúkọ rẹ pe ṣàlàyé pé ọmọ ile ẹ̀kọ́ to wa ni ipele àgbà fi èyí kékeré ẹni ọdun mọ́kànlá náà silẹ gẹgẹ bii ẹni to ti kú ni pẹlu bi ara rẹ ṣe kún fún àgbàrá ẹ̀jẹ̀.

Jibril

Oríṣun àwòrán, PR Nigeria

"Lẹyin àkókò díẹ̀ Jubril pẹ̀lú irora wọ ara rẹ lọ si ọ́fíìsì adari ilé ẹ̀kọ́ naa níbi to ti padà ṣubú lu ilẹ̀ ti ko le gbéra mọ".

Wọn ní ọwọ tí tẹ arakunrin to ṣiṣẹ́ aburu yii èyí tí wọn ni o ti wa lara awọn to n mu oogun oloro wọn si ti gbé e fún Ọlọpaa fún ìwádìí.

Gẹgẹ bi ìròyìn ṣe sọ ọ, Jubril to wa ni àìlera báyìí jẹ ọmọ olóògbé Adajọ agba ni ile ẹjọ́ gíga Ìpínlẹ̀ Kano, Sadi Mato, tí ìyà rẹ Haji yà Aisha si jẹ oṣiṣẹ ijọba to ti fẹ́ ọkọ míì.

Ẹwẹ, Iroyin ni ọkọ rẹ to ku ni bàbá fún Jubril ẹni tí wọn pé láti ilé ẹ̀kọ́ ni wọn ní o ti ń sọ fún wọn kí wọn ma fi ẹjọ́ ìkọlù náà sún àmọ́ BBC kò lè fìdí èyí múlẹ̀.

Titi di asiko ti a n ko ìròyìn yìí jọ, kò si ẹni tó leè sọ ibi tí àwọn Ọlọpaa bá ìwádìí wọn dé.