Wukari monarch death: Ìrírí mi rèé tí mi ò fi lè gbà kí ọkọ mi tún sín òkú Ọba kankan wọ igbó mọ́ - Ìyàwó Atobe

Oríṣun àwòrán, Sallah Atobe
Iyawo ẹni iyi, Ẹlẹṣin ijọba ilẹ Wukari nni to ti di gbajugbaja bayii tori o da nikan gbe oku Ọba wọn pọn lori ẹṣin lọ sinu igbo, Arabinrin Mercy Atobe ti ni ibẹru to kun aya oun kii ṣe kekere rara oun ko si ni gba ki ọkọ tun wọ inu igbo aginju mọ.
Ọkọ rẹ, Sallah Atobe lo ṣe ohun aramanda ati iyalẹnu lọjọ Satide ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kini ọdun gẹgẹ bo ṣe da gun ẹṣin toun nikan si gbe oku Ọba ilu wọn to waja. oloogbe Aku-Uka ti ilu Wukari, Ọmọwe Shekarau Angyu Masa-Ibi to jade laye ninu oṣu Kẹwa ọdun to kọja lọ inu igbo kijikiji.
Iya ọlọmọ mẹta to jẹ iyawo Sallah ba ara rẹ ni ile iwosan ni kete ti ọkọ r bẹrẹ irinajo naa lọ sinu igbo Nando o si ṣalaye bo ṣe dede ba ara rẹ ni ipo aisan lasiko isinku naa.
"Lọjọ naa, mi o le jade kuro ninu ile nitori bi ọkan mi ṣe n dun "ki ki ki" ati ibẹru, ṣe ni ara mi kan ṣaa n ṣe mi bakan bakan lẹyin rẹ, mo kan dede ba ara mi nile iwosan, mi o si le ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ".
Arabinrin Mercy ni inu oun dun daadaa bi oun ṣe ri ọkọ oun nkan to si jẹ ki ara oun ya pada ni ileewosan to wa niyẹn.

Oríṣun àwòrán, Sallah Atobe
"Ni kete ti mo ri i ni ara mi kan ya lọwọ kan nitori ọkan mi wa balẹ pe ọkọ mi ti pada de.
Ni bayii, mi o ni gba ko lọ ibi kankan mọ rara ka ma tilẹ sọrọ inu igbo, a o jọ wa pọ ni", o n sọ eyi gẹgẹ bo ṣe n rẹrin.
Arabinrin Mercy fi kun un pe o n da inu oun dun bi ọkọ rẹ ṣe wa di gbajugbaja ati akinkanju ni ilu awọn ti gbogbo eeyan si n yin in.
Lakotan, oun naa ni oun ni ibọwọ pupọ fun aṣa ati iṣe awọn oun ko si ni fẹ ko pari tabi yipada.
Itan ranpẹ nipa awọn ẹya Jukun

Oríṣun àwòrán, Tijjani Sale Angyui

Oríṣun àwòrán, Sallah Atobe
Gẹgẹ bi itan wọn, awọn eeyan Jukun tẹ ilu Wukari do ni ọọrundunrun kẹtadinlogun.
Wukari jẹ kan lara awọn aarin gbugbun iha Guusu to jẹ ọna katakara to so ilu Bauchu, Katsina, Kano ati Borno pọ.
Lodi si ohun ti ọpọ n sọ lori ayelujara pe ẹlẹṣin ọhun ti mọ lati kekere pe bi ọba ba ku, oun ni yoo sin oku rẹ lọ inu igbo, Ọmọba Jollu Agbu Masa-Ibi sọ pe irọ ni.
"Bi wọn ṣe maa n mu Ẹlẹṣin Ọba yii ni ṣaaju maa n waye ni ọjọ bii melo kan ṣaaju aṣa eto isinku naa lẹyin ti wọn ba ti bi awọn irumọlẹ.
"Torinaa kii ṣe ootọ pe idile kan pato lo n ṣe iṣẹ yii ko si sẹni to maa n mọ lati kekere pe oun ni yoo ṣe iṣẹ naa.
Gẹgẹ bi aṣa ibilẹ, Ẹlẹṣin ọ̀hun ni yoo sin Aku lọ jinajina inu igbo aginju Nando nibi ti yoo ti pade awọn baba nla baba rẹ tori o ni ibi ti awọn to ba n sin in lọ ti gbudọ boju wẹyin ki wọn pada sile..
Bawo ni wọn ṣe n ṣe ilana eto isinku yii?

Oríṣun àwòrán, Sallah Atobe
Ni ibamu pẹlu itan ilu Wukari, "Aku kii waja. O kan rekọja" lati lọ ba awọn baba nla rẹ ni
Ni ti aṣa ọ̀hun, wọn ti bẹrẹ si ni gbaradi lati bii oṣu mẹta si meje gẹgẹ bi Àrẹmọ to ba BBC sọrọ ṣe sọ ọ.
Gẹgẹ bi awọn fọto ati fidio to tan ka ori ayelujara, awọn eeyan jakejado ni yoo to ara wọn jọ lati yẹ Aku to n rinrinajo naa lọ ba awọn baba nla wọn.
Bakan naa, awọn obinrin alagbara nilu yoo gẹ irun ori wọn nigba ti awọn ọkunrin yoo duro de ki ẹlẹṣin to sin oku ọba wọn wọ igbo de pada.















