Samuel Ortom: A ti fi kún owó ìtanràn fún ẹni tó ba da ẹran jẹ̀ nígboro Benue- Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue

Darandaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹnikẹ́ni tó bá daranjẹ ko láàárín ìgboro yóò san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Náírà - Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue, Samuel Ortom

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue Samuel Ortom tí buwọ́lu àtúnṣe sí òfin tó sọ dída ẹran jẹ̀ ní ìta gbangba di èèwọ̀ àti ìdásílẹ ibùjẹ ẹran ti ọdún 2017.

Òfin yìí ti wá fi òté le wí pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú pé ó da ẹran láàárín ìlú tàbí ẹsẹ̀ kùkú tàbí apá ibì kankan fún ìgbà àkọ́kọ́ ní Ìpínlẹ̀ náà yóò san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Náírà.

Kini ofin yii yoo ṣe bayii?

Bákan náà ni òfin yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú fún ẹ̀ṣẹ̀ kan náà fún ìgbà kejì yóò san mílíọ̀nù kan Náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.

Nígbà tó ń buwọ́lu òfin náà ní Ọjọ́ bọ̀, ní gbọ̀ngán Banquet ilé ìjọba ní ìlú Makurdi, gómìnà Ortom ní àwọn ṣe àfikún àwọn owó ìtanràn látàrí bí ohun gbogbo ṣe rí lọ́wọ́ yìí lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Kaun

Ijiya wo lo wa tọ si arufin yii?

Ortom ni fún ìdí èyí, màlúù kan tí wọ́n yóò gba ìdáǹdè rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún méjì Náírà tẹ́lẹ̀ ti di ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta Náírà báyìí látàrí bí owó àwọn ohun tí wọ́n fi ń tọ́jú àwọn màlúù náà ni àyè tí wọ́n ń kó wọn sí ti gbówó lórí.

Bákan náà ni òfin yìí ṣe àlàkakẹ̀ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá tàbí sísan owó ìtanràn mílíọ̀nù márùn-ún Náírà fún ẹni tí ó bá ní kí àwọn ọmọdé máa dá ẹran láàárín ìgboro.

Àwọn owó ìtanràn mìíràn ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta Náírà lórí màlúù kan, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lórí Ẹlẹ́dẹ̀ kan àti ẹgbẹ̀rún kan Náírà lórí adìẹ.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Gómìnà tún ṣàlàyé pé ẹni tí wọ́n bá mú nǹkan ọ̀sìn rẹ̀ tí kò sì wá gbà á ní ọjọ́ náà yóò san àlékún ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún Náírà, tí kò bá sì wá gbà á lẹ́yìn ọjọ́ méje, òfin fàyè gba ìjọba láti lu nǹkan ọ̀sìn bẹ́ẹ̀ ní gbàǹjo.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe làlùyọ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí èmi náà ń lọ ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba - Raymond Adegoke

Ṣaájú ni gómìnà Ortom ti tẹ́ pẹpẹ òfin náà síwájú ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ náà fún àtúnṣe lójúnà à ti wá ojútùú sí àwọn tó ń tẹ òfin náà lójú mọ́lẹ̀.

Àkọlé fídíò, Eba

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun to kọjá ní ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Benue buwọ́lu òfin náà lẹ́yìn ìjíròrò gbogbo ilé.