Libya Returnee: Ọpẹ́lọpẹ́ orúkọ Ooni Ile Ife ló kó mi yọ ní Libya lẹ́yìn ti mo lóyún ní óko aṣẹ́wó ti wọ́n tá mi sí
Ariwo pe ki awọn ọdọ Naijiria ṣọra fun ẹtan awọn to n ko wọn rin irinajo lọ si ilẹ okeere lọ ṣe iṣẹ aṣẹwo ni BBC Yoruba n pa lasiko yii.
Ọpọ awọn ọdọ obinrin ni wọn n jade sita bayii lati sọ ohun ti oju wón ri ni ilẹ okeere paapaa ni Libya.
Wọn n tan wọn ni ki wọn to so awọn ọdọbinrin yii di aṣẹwo nilẹ okeere.
- Lekan Balogun ni Olubadan kàn, kó sí àríyànjiyàn níbẹ̀ - Ladoja, àwọn afọbajẹ Ibadan sọ̀rọ̀
- Ìkọlù darandaran àti àgbẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn: Ènìyàn márùn-ún, ọ̀pọ̀ ilé bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ
- Gani Adams ṣàlàyé bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ń dènà ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho ní àhámọ́
- Ikú Esther Anguju ní ìpínlẹ̀ Nasarawa dá inú fu, àyà fo kalẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ọkọ rẹ̀
- Mọ̀ síi nípa àǹfàní tí lílo Àlùbọ́sà Aáyù lè fún ìlera ìwọ àti ẹbí rẹ
Fatimah, ọkan lara awọn ti iya jẹ ni Libya lo tun jade sọrọ loni lori bi o ṣe fi ọsẹ mẹta rin ninu aṣale de Libya ki Azeez to ta a fun Michael to tun Fatimah ta si oko asewo nibẹ.
O ni: Nitootọ ni Azeez maan ko awọn eeyan lọ silẹ okeere ṣugbọn mi o mọ pe aṣẹwo lo nko wọn lo ṣe ni Libya.
Fatimah sọ nipa bi ọmọkunrin ara Ghana kan se yọ oun loko aṣewo ati bi wọn ṣe pada wa fọ koropọn ọkunrin naa.
O ni wọn pa ọkunrin naa nitori pe o pada ra oun kuro ni oko ẹru.
- Wo awọn iroyin manigbagbe to waye ni ọsẹ yii
- Mọ̀ sií i nípa Oba Yesufu Asanike , Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Ìdí tí wọn kii fi jẹ́ kí obìnrin jẹ Ọ̀ọ̀ni ni Ile Ife
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Wo àwọn sinimá mẹ́wàá tó gbé sinimá Yorùbá sáyé
O ni niṣe ni wọn lu omo Ghana i oun loyun fun lẹyin ti o ra oun kuro nile aṣẹwo naa pa pẹlu omije.
Fatimah ni pe orukọ Oba Adeyeye Ogunwusi ti oun da ni 'embassy' ni oun fi moribọ pada wa si Naijiria pẹlu ẹmi oun.

Oríṣun àwòrán, Others
Bakan naa ni Fatimah gba awọn ọdọbinrin Naijiria ni imọran pe ki wọn ṣọra fun ẹtan pe a n lọ sile oyinbo to gbode kan yii nitori pe Canada ni oun fẹ lọ ki oun to di ero Libya

