Libya nira láti gbé
Ẹtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀
Ẹgbẹlẹgbẹ ọ̀dọ́ Nàìjíríà ló ń wáṣẹ́ ajé lọ sílẹ̀ òkèèrè
Ọrọ àìríṣẹ́ ṣe àwọn ọdọ Naijiria ti sọ wọn di oṣiṣẹ àwọn iṣẹ ti kò pọ́n nilé nílẹ̀ okeere bii Libya, Italy, France àti bẹẹ bẹẹ lọ.
BBC Yorùbá fọrọ wa diẹ ninu àwọn tijọba ko de lati Libya lẹnuwo.
Wọn gbagbọ pe, o sàn lati lọ jiya ni Yuroopu ju ki ebi máa pa awọn nile ni Naijiria lọ.
Ọna abayọ ti awọn to ku ti wọn ṣi n jiya ni Libya fi le wa sile ni ki ijọba Naijiria rọgun si àwọn ti wọn ti ko de lapa, ki wọn fun wọn niṣẹ oòjọ́ tabi ki wọn da wọn l'ókowò.
Igbesẹ yii yoo jẹ ko wu awọn to ku lọhun lati wale.

Nkan ti ojú wa n ri lọhun pọ gan an ni, ọ̀pọ̀ obinrin ni wọn fi ń ṣaṣẹwo nilẹ okeere bayii.
Wọn gbà pe, ó sàn lati ta awọn nkan ìní wọn lati ri owó lọ silẹ okeere ju ki wọn duro si Naijiria ti kò ti si ounjẹ ati ètò ààbò to yaranti.
