Minimum Wage: Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi buwọ́lu ₦30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, @OfficialGYBKogi

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ti buwọlu ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bii owo oṣu to kere julọ fun awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ naa.

Akọwe ijọba ipinlẹ ọhun, Folashade Arike Ayoade lo kede igbesẹ yii lẹyin ipade kan pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ niluu Lokoja.

O ni ajakalẹ arun Covid-19 to mi gbogbo agbaye titi lo ṣokunfa bi awọn ko ṣe tete gbe igbeṣe lori owo oṣu tuntun naa, eyii ti awọn ti bori rẹ bayii.

Akọwe ijọba naa tun gboriyin fun ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ ọhun fun ifọwọsowọpọ ati suuru wọn.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ifọwọsọwọpọ ẹgbẹ naa lo mu ki awọn ṣe aṣeyọri lori igbesẹ tuntun naa.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Nigba to n sọrọ, igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Edward Onoja gboriyi fun awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ ọhun fun akitiyan ati ifọwọsọwọpọ wọn pẹlu ijọba lori ọrọ naa.

O ni inu oun dun pe wọn ko jẹ ki ọrọ naa yọri si iyanṣẹlodi ki awọn to yanju rẹ.

Àkọlé fídíò, Segun iberu

Lẹyin naa lo juwe gomina Yahaya Bello gẹgẹ bii adari rere, ati ẹni to ni ifẹ awọn oṣiṣẹ rẹ lọkan.

Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC, ẹka Kogi, Onuh Edoka sọ pe inu oun dun pe awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Kogi ti ba awọn ojugba wọn lawọn ipinlẹ mii dọgba bayii nipa owo oṣu naa.

Àkọlé fídíò, Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá