Nnamdi Kanu court trial: Iléẹjọ́ tún sún ìgbẹ́jọ́ olórí ẹgbẹ́ IPOB Nnamdi Kanu síwájú

Nnamdi Kanu
Àkọlé àwòrán, Nnadmdi Kanu, nye ndu ndị Ipob bụ onye abụọ kwụ n'aka nri. E sere foto a

Ileẹjọ tun ti sun igbẹjọ olori ẹgbẹ ajijagbara nilẹ Ibo, IPOB, Nnamdi Kanu niluu Abuja siwaju.

Kanu foju ba ileẹjọ ni Ọjọru lori ẹsun igbesunmọmi, pipe fun iyapa ẹya Ibo lara Naijiria ati gbigbe irọ kiri nipa aarẹ Muhammadu Buhari.

Ijọba tun fikun awọn ẹsun ti wọn kan Kanu ninu igbẹjọ to waye ni oṣu kinni ọdun 2022 yii.

Ṣugbọn ti sọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.

Amọ, adajọ Binta Nyako ileẹjọ giga ijọba apapọ niluu Abuja ti sun igbẹjọ naa di ọjọ kẹjọ oṣu kẹrin ọdun yii.

Kanu ti n pe fun iyapa ẹya Ibo kuro lara Naijiria tipẹ, o ni ki awọn Ibo da orilẹede Biafra silẹ.

Kanu to ni iwe igbeluu ilẹ Gẹẹsi ati orilẹede Naijiria lọwọ da ẹgbẹ IPOB silẹ ni nkan bi ọdun mẹwaa sẹyin.

Nnamdi Kanu yóò tún fojú balé ẹjọ́ lónìí, oun tó lè ṣẹlẹ̀ rèé

Igbẹjọ adari awọn ajijagbara Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu yoo tẹsiwaju lonii, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji, ọdun 2022, nile ẹjọ giga to wa niluu Abuja.

Kanu n koju ẹsun marun un ọtọtọ to da lori igbesumọmi, iṣọtẹ, iyapa ati jijẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ti ijọba apapọ ti fofin de.

Wọn tun fẹsun kan Kanu pẹ o n kede awọn ọrọ kobakungbe nipa Aarẹ Muhammadu Buhari, amọ o ti sọ pe oun ko jẹbi ọkankan ninu gbogbo ẹsun naa.

Lẹyin ti Kanu ti kọkọ sọ pe oun ko jẹbi afikun ẹsun marundinlogun ti ijọba apapọ fi kan, agbẹjọro ijọba apapọ, Shuiabu Labaran, rọ adajọ to n gbọ ejọ ọhun, Binta Nyako, lati tete bẹrẹ ẹjọ naa.

Labaran sọ pe awọn ti ni awọn eeyan nilẹ ti yo jẹri tako Kanu.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Ẹwẹ, agbẹjọro Kanu, Mike Ozekhome, to jẹ agbẹjọro agba ni Najiiria, ni oun ko ni gba ki ẹjọ naa bẹrẹ nitori awọn ti pe ẹjọ meji tako ẹjọ ti ijọ apapọ pe tako Kanu.

O ni ohun ti awọn n fẹ ni ki ile ẹjọ naa da ẹjọ ti wọn pe tako Kanu nu, ki wọn si tu silẹ ahamọ lọna ati le maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia.

Lẹyin naa ni adajọ to n gbọ ẹjọ naa sun si oni, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Keji, ti a wa yii.

Àkọlé fídíò, Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

Ohun to le ṣẹlẹ̀ nibi igbẹjọ naa lonii

Ile ẹjọ naa ti sọ pe aago kan ọsan ni igbẹjọ naa yoo bẹrẹ.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa

Ile ẹjọ ọhun tun paṣẹ pe ki awọn agbofinro maṣe di awọn ọna to yi ile ẹjọ naa ka ki awọn eeyan miran to ni ẹjo le ri aye wọ ile ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab

Ẹwẹ, iroyin ni o ṣeeṣe ki agbẹjọro Kanu pe ẹjọ tako ibi ti igbẹjọ naa ti n waye nitori bi ijọba Naijiria ṣe ji olubara rẹ gbe lati orilẹ-ede miran wa si Naijiria.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...