Properties Seized From Military Officer: Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé dúkìá ọ̀gá olọgun tí iye rẹ̀ tó ₦10.9b

Properties Seized From Military Officer

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti gbẹsẹle awọn dukia kan to jẹ ti ọga agba kan ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria.

Bo tilẹ jẹ EFCC kọ lati kede orukọ ọgagun maa, wọn ni iye owo dukia ọhun le ni biliọnu mẹwaa naira.

Gẹgẹ bii ohun ti EFCC sọ, ọgagun naa ra, o si tun n ṣakoso awọn dukia ọhun nipasẹ awọn ẹlomiran lọna ati dabo bo ara rẹ ki aṣiri rẹ ma baa tu.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ EFCC, Wilson Uwujaren fi lede lo ti sọ pe adajọ ile ẹjọ giga kan n iluu Abuja, N.E Maha ti paṣẹ pe ki wọn gbẹsẹle awọn dukia ọhun.

Aṣẹ ile ẹjọ

Atẹjade ọhun ni "Adajọ N.E. Maha ti paṣẹ pe ki a gbẹsẹ le dukia mẹrinlelogun to jẹ ti ọgagun kan nileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, amọ to n ṣakoso awọn dukia ọhun labẹ orukọ ẹlomiran."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

"Aṣẹ yii lo n waye lẹyin ti EFCC bẹ ile ẹjọ naa lọwẹ ninu oṣu Karunn un ọdun 2020 lori awọn dukia naa."

"Ile ẹjọ ọhun ti kọkọ sọ pe ki ẹnikẹni to ba lodi si ki ijọba gbẹsẹle awọn dukia naa wa sọ ni gbangba... amọ lẹyin ti ko si ẹnikẹni to tako igbesẹ naa, adajọ Maha ti wa paṣẹ pe ki ijọba aapọ gbẹsẹle gbogbo dukia ọhun."

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

"Lara awọn ipinlẹ ti awọn dukia naa wa ni Kano, Kaduna, Borno ati Cross River, lara awọn dukia ọhun si ni ilẹ, ile itaja ati ile epo bẹntiro ti iye gbogbo rẹ to ₦10,935,000,000.00."

Die lara awọn dukia naa ree

  • Ile epo bẹntiro mẹsan an ni ipinlẹ Kano
  • Ile itaja gaasi ati ṣọọbu ọgbọn ni Kano
Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...
  • Gbọgan ode ariya ni Kano
  • Ile alaja mẹta to ni ṣọọbu mejidinlogun ni Kano.
Àkọlé fídíò, Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab
  • Ile itaja alaja mẹta to ni ṣọọbu mẹ́rìndínláàdóje ni Kano
  • Ileeṣẹ ti wọn ti n mọ bulọọki ni Kano, ati oniruru dukia mii lawọn ipinlẹ miran.
Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi