Osun Crisis Oyetola and Aregbesola: Wọ́n fẹ́ ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ Aregbesola la ṣe da ìbọn bolẹ̀ - NSCDC

Aregbesola ati Oyetola

Oríṣun àwòrán, Others

Àwọn tọ́ọ̀gì Aregbesola ló da wàhálà sílẹ̀ l'Osun - Ọlọ́pàá

Àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ti di ẹ̀bi làásìgbò tó wáyé lọ́jọ́ Ajé, ní agbègbè Old Garage, Osogbo, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà ru Mínísítà fọ́rọ̀ Abẹ́lẹ́, Rauf Aregbesola.Aregbẹsọla kìí ṣe Olọ́run, iṣẹ́ Oyetola ló máa fọhùn lọ́jọ́ ìdìbò- Ismail Omipidan

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Yemisi Opalola lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ní ṣàdédé ní àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ààbò ara ẹni làbò ìlú, NSCDC àti ti Immigration tí wọ́n kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú Aregbesola dédé da ìbọn bolẹ̀ ní Old Garage àti MDS nígbà tí wọ́n ń kọjá níbẹ̀.

Opalola ní ìbọn yínyìn yìí dá ìfòyà sọ́kàn àwọn ara àdúgbò náà, tí wọ́n sì ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn àti pé ọta ibọn mẹ́tàlá ni àwọn ṣà nílẹ̀ lẹ́yìn tí ọkọ̀ Mínísítà náà lọ tán.

Ó ní ìwà yìí kò dára tó bó ṣe jẹ́ dída àláfíà àwọn ara ìlú láàmú ṣùgbọ́n tó ní ẹnìkankan kò farapa níbẹ̀.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Kí ni ajọ aṣọ alaabo NSCDC wí?

Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ àjọ ẹ̀ṣọ́ ààbò ara ẹni làbò ìlú, NSCDC, tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun, Olabisi Atanda ní àwọn ọmo ìta kan ló fẹ́ ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà lásìkò tó ń kọjá ní Old Garage ni àwọn ṣe da ìbọn bolẹ̀.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta, Atanda ní nǹkan bí aago méje ku ogún ìṣẹ́gún ní àwọn ọmọ gàǹfé náà gbìyànjú láti ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ Aregbesola ṣùgbọ́n tí àwọn tètè rí ìkápá lórí rẹ̀ bá àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tó tẹ̀lé Mínísítà náà ṣe jí gìrì sí ojúṣe wọn.

Àkọlé fídíò, Kong Thong: Àwọn òbí máa ń súfèé kọrin tàbí hu láti pe ọmọ tó bá dàgbà

Bákan náà ló ní, ọ̀gá àgbà àjọ NSCDC ìpínlẹ̀ Osun, Emmanuel Ocheja ti sọ àrídájú rẹ̀ pé àjọ náà kò ní kùnà láti pèsè ètò ààbò tó péye fún àwọn ara ìlú nígbà gbogbo.

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni àwọn olùfẹ̀hónúhàn yabo ọ́fììsì àjọ NSCDC tó wà ní ìlú Osogbo lórí bí wọ́n ṣe dàbọn bolẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ Mínísítà Rauf Aregbesola kọjá ní agbègbè Old Garage ní Osogbo.

Àkọlé fídíò, Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà lábẹ́ àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìpínlẹ̀ Osun (NAOSS) gbé onírúurú àkọ́lé lọ́wọ́ bíi "NSCDC ń dúnkokò mọ́ àwọn ènìyàn wa l'Osun", "NSCDC ṣe ààbò wà fún wa", "NSCDC, nítorí ààbò la ṣe gbà yín kìí ṣe láti pa àwọn ènìyàn wa", àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àkọlé fídíò, Bad Boy Timz: Fásitì ni mo wà tí mo fi kọrin ‘Gbẹ́sẹ̀ lọ́kọ̀ọ́ọ̀kan’ tó sọ mi di gbajúmọ̀

Ààrẹ NAOSS, Moshood Yusuf nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó ṣàgbékalẹ̀ ìwé ìpẹ̀jọ̀ tí wọ́n kọ sí ọ̀gá NSCDC ní àwọn òṣìṣẹ́ tó lọ́wọ́ níbi ìbọn tí wọ́n yìn náà gbọ́dọ̀ fojú winá òfin.

Ṣaájú, àjọ NSCDC kò fẹ́ kí àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà rí ààyè wọ inú ọgbà wọn tí wọ́n sì ṣe àwọn akọ̀ròyìn tó wà níbẹ̀ léṣe.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Àwọn ọmọde tí mò ń bá ṣe ‘skit’ ló dáwó jọ fún mi nígbà tí àìsàn inú dé sí mi

IPAC dá sí aáwọ̀ Aregbesola àti Oyetola

Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìpẹ̀tùsááwọ̀ àárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, (IPAC) ti rọ àwọn Aregbesola àti Gómìnà Gboyega Oyetola láti gba àláfíà láàyè kí ìpínlẹ̀ Osun le tẹ̀ síwájú.

Àkọlé fídíò, Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

Alága IPAC, Wale Adebayo, ní ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín àwọn àgbà olóṣèlú méjéèjì yìí le dogun dọ̀tẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà tí wọn kò bá kíyè sára.

Ó fi kun pé yóò tún ṣàfihàn ìpínlẹ̀ Osun lọ́nà tí kò dára sí aráyé.

Àkọlé fídíò, 'Ìyá Tíṣà lòdì sí kí n mutí, fagbó tàbí sìgá'