Eating Placenta: Ẹ wo ìdí táwọn ìyálọ́mọ fi ń jẹ Olubi àti ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí wọn ń gbà jẹ ẹ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan

Yopruba ni tibi tire la dale aye, tibi tire la se ẹ́da eeyan, bi aye ire se wa, naa ni aye ibi wa.

Ni ọjọ ikunlẹ ti alaboyun ba bimọ tan, bi wọn ba se n gbe ọmọ tuntun jade, ti Yoruba gbagbọ pe ire ni, naa ni wọn yoo tun gbe asopọ ẹjẹ ati ẹran jade ni ikun alaboyun, ti wọn n pe ni Olubi.

Olubi ọmọ yii si lo jẹ iwulo fun ẹjẹ ọrun lasiko to ba wa ninu oyun, eyi to n pese afẹfẹ́ fun lati ara iya rẹ amọ olubi yii ko wulo kankan mọ̀, boya fun ọmọ tabi iya rẹ lẹyin ibimọ.

Amọ iyalẹnu lo jẹ lati gbọ pe awọ iyalọmọ kan maa n se olubi ọmọ yii, ti wọn yoo si jẹ bii ounjẹ lẹyin ti wọn ba bimọ tan nitori awọn idi kjan to han si awọn nikan.

Nibayii, awọn onimọ iwadii ni Fasiti Northwestern ti wa sekilọ fun awọn iyalọmọ lati dẹkun jijẹ olubi ọmọ wọn nitori ọpọ ewu to wa ninu rẹ.

Àkọlé fídíò, "A gbúdọ̀ wẹ̀ ọmọ tuntun pẹ̀lú epo pupa, kàìnkàìn ìbílẹ̀ àti ọṣẹ dúdú'

Wo oniruuru ọna tawọn iyalọmọ n gba jẹ Olubi ọmọ:

Awọn onimọ iwadii yii ni olubi jẹ okun to n gbe afẹfẹ oxygen atawọn eroja mi lati ara iya si ara ọmọ ninu oyun, okun ọhun tun maa n fa awọn idọti inu ẹjẹ ọmọ kuro.

Wọn fikun pe jijẹ olubi yii ko ṣiṣẹ kankan lara awọn iya ikoko, ko si tọ ki wọn maa jẹ.

Aṣa ki iya ikoko maa jẹ olubi ọmọ yii bẹrẹ si n gbilẹ si lẹyin ti awọn gbajumọ kan atawọn alẹnulọrọ lori ayelujara bẹrẹ si n sọ iriri wọn lẹyin ti wọn jẹ olubi ọmọ wọn tan.

Iroyin ni awọn obinrin kan maa n jẹ olubi naa ni tutu lai ṣe e, nigba ti awọn mii a maa se tiwọn, ti awọn miran a si maa yan ti wọn ki wọn to jẹ.

Yatọ si jijẹ Olubi, awọn mii maa n lọ olubi naa pẹlu awọn eso mii, ti wọn a si mu bii ẹni mu ẹlẹrindodo.

Àkọlé fídíò, Stem Cell treatment: Àrùn tó lé ní 80 ni àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó leè fi ìwọ́ àti olubi

Isẹ ti awọn iyalọmọ ni Olubi n se ninu ara ti wọn fi n jẹ ẹ:

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ti sọ pe olubi dara fun itọju ọkan to rẹwẹsi, ara rirẹ ati fun omi ọmu, ṣugbọn awọn onimọ iwadii yii ni ko si iwadii kankan ninu imọ ijinlẹ to fidi ọrọ naa mulẹ.

Wọn ni "Ninu imọ eto ilera, bii idọti ni olubi ọmọ ri lẹyin ọjọ ikunlẹ nitori awọn kokoro aifojuri kan maa n wa lara rẹ."

"Nitori naa a ko fọwọ si ki awọn eeyan maa jẹ ohun to ni kokoro aifojuri lara nitori ewu to wa nibẹ."

Wọn sọ siwaju si pe "Pupọ obinrin to n jẹ olubi ọmọ wọn n ṣe bẹẹ lode oni nitori wọn ri awọn akẹgbẹ wọn to n ṣe bẹẹ.

Ṣugbọn imọran ti wa ni pe ki wọn dẹkun ati maa ṣe bẹẹ nitori ko si iwadii to fidi rẹ mulẹ pe jijẹ olubi ọmọ n ṣe ara loore."

Awọn onimọ iwadii yii wa pari ọrọ wọn pe, lootọ ni pe olubi ni awọn eroja amarajipepe ati ọra ninu, ṣugbọn awọn iya ikoko le ri irufẹ awọn eroja bẹẹ ti wọn ba n jẹ ounjẹ gidi dipo olubi.

Lẹyin naa ni wọn kilọ fun awọn obinrin lati dẹkun gbogbo iwa ti yoo mu ewu lọwọ fun wọn ati ọmọ tuntun, ki wọn si maa kan si dokita wọn ki won ṣe ohunkohun lẹyin ọjọ ikunlẹ.