Umbilical cord: Àìsàn Màrùndíláàdọ́rùn ni ìwọ́ ọmọ tuntun le wòsàn

Umbilical cord: Àìsàn Màrùndíláàdọ́rùn ni ìwọ́ ọmọ tuntun le wòsàn

Oríṣun àwòrán, Others

Adarí ilé iṣẹ́ ìṣègùn kan Toluwalope Ogunlẹyẹ ti rọ àwọn abiyamọ láti máa yọ̀nda ìwọ́ (Umbilical Cord) ọmọ wọn si àwọn ilé ìkẹjẹ̀ sí jákèjádò Naijiria.

Ó ní èyí ni láti le máa dóòlà ẹ̀mí àwọn ènìyàn to ni ààrùn kan tàbi òmíràn.

Ogunleye sọ èyí nínú ìpàdé orí ayélujára nílùú Eko pé ètò náà wáyá láti pe àkíyèsí àwọn ènìyàn si pàtàkì ìwọ́ ọmọ fún ètò ìwòsàn láwùjọ.

Àkọlé fídíò, Ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn

Adarí ilé iṣẹ́ ètò ìlera náà sàlàyé pé, ìwádìí ti fi hàn pé, ìwọ́ ọmọ mii ó wùlò jùlọ fún ìtọ́jú àwọn ààrùn kan ti o sì lé wúlò fun ìtọ́jú àwọn ààrùn márùndínláàdọ́rún kan.

Àwọn ààrùn náà ni ààrùn

  • Fòníkú-fọ̀la dide
  • Etí dídi.
  • Àwọn ààrùn to niṣe pẹ̀lú ọpọlọ abbl

O fi kun pé, wọ́n ti lòó láti fi ṣe ìtọ́ju ẹni to ni ààrùn fòníkú, fọ̀la dìde.

Ogunleye ni kíkó ìwọ́ ọmọ wẹ́wẹ́ pamọ́ jẹ̀ ǹkan tó le wáye ni ẹ̀ẹ̀kan lọ́ja ayé ènìyàn láti rí ìwòsàn fún àwọn ààrùn to lágbára púpọ̀, ó fi kún pé, ibi ti wan ti máa n ri irú èròjà yìí tẹ́ẹ̀ ni inú mùdùnmúdùn inú egungun ènìyàn.

Ó ní ìwòsàn àkọ́ka ti wọ́n lo sítẹ́mú sẹẹ̀lì fún wáye ni ọdún 1988 tí ó sì ni àṣeyọri, ó ni ẹni ti wọ́n ṣe fún ni ọmọkunrin kékere kan to ni ààrun ti wọ́n ń pè ni "Fanconi's Anemia, ó sì niṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti ko já geere. Wọ́n gba ìwọ́ àbúrò rẹ ti wọ́n bi wọ́n sì lòó láti fi ṣe ìwòsàn rẹ̀.

Bákan náà lo ni ìwádìí ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ pé ìwọ́ yìí le dí egungun, ẹran ara, ọkan, àti oníruyuru ẹ̀yà ara.