How to prevent Sudden Infant Death: Nkan mẹ́sàn-án tí o le ṣe láti dènà ìkú ọmọ tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iku ojiji to ma n pa awọn ọmọ tuntun, eyi ti awọn onimọ n pe ni Sudden Infant Death Syndrome (SIDS) ma n waye nitori oriṣiriṣi nkan.
Ọpọ iku yii si lo ma n ṣẹlẹ laarin oṣu mẹfa akọkọ ti ọmọ ba de ile aye. Yatọ si pe afọwọfa le fa a, ọmọ ti oyun rẹ ko pe oṣu mẹsan-an tabi ti ko tobi daadaa nigba ti wọn bi naa wa ninu ewu iku ojiji.
Iku ojiji yii ṣaba ma n ṣẹlẹ lasiko ti ọmọ tuntun ba sun.
Nitori naa, ẹ wo awọn nkan mẹsan-an to le dena iku ojiji fun ọmọ tuntun.
Jẹ ki ọmọ tuntun fi ẹyin sun
Iwadii awọn onimọ iṣegun oyinbo fihan pe ewu to le fa iku ọmọ tuntun wa ninu ki ọmọ ma a fi ẹgbẹ sun tabi da ikùn bolẹ sun. Idi ni pe ọmọ to ba fi ẹgbẹ sùn le yi, ko si doju bolẹ. Ti iru ọmọ bẹ ẹ ba doju bolẹ si ori ibusun, ibusun le di eemi to n jade tabi wọle si iho imu ọmọ tuntun naa. Eyi to le fa iku.
Titẹ ọmọ tuntun si ori ibusun to le
Lati le dena ki aisi eemi pa ọmọ tuntun, o ṣe pataki lati tẹ wsn si ori ibusun 'mattress' to le daadaa, tabi awọn ibusun ti wọn ṣe fun ọmọ tuntun.
O ko si gbọdọ fi ohunkohun bi i aṣọ ibora, irọri tabi awọn nkan iṣere si ori ibusun naa, eyi to le fun ni ọrun pa.
Awọn onimọ iṣegun ni US Department of Health and Human Services sọ pe eyi ma n mu adinku ba ijamba oju orun to le pa ọmọ tuntun.
Ma ṣe fa siga ni ẹgbẹ ọmọ tuntun
Awọn onimọ iṣegun oyinbo sọ pe o dara ki obinrin to ba n mu siga fi opin si lasiko to ba wa ninu oyun, lati le dena iku ọmọ tuntun.
Iwadii fihan pe awọn ọmọ ti iya wọn ba fa siga ninu oyun wọn kii ṣaba tobi bo ṣe yẹ lasiko ibi wọn - eyi si jẹ ara nkan to n fa iku ọmọ tuntun. Bakan naa, fifa siga nitori ọmọ tuntun le ṣeku pa a.
Gbe ọmọ rẹ si tosi rẹ
Iwadii fihan pe ko fi bẹ ẹ si ewu iku fun ọmọ tuntun to ba sun sinu yaara kan naa pẹlu iya rẹ.
Idi ni pe iya naa yoo mojuto daadaa.
Ṣugbọn ṣa, iru iya bẹẹ gbọdọ kiyesara ki o ma sun lọ lasiko to ba n fun ọmọ ni ọmu.
Eyi lewu, nitori pe ọyan rẹ le di ọmọ ni imu, ti ko ni i le mi daadaa, to si le fa iku.
Fifun ọmọ ni ọyan daadaa
Oriṣiriṣi anfaani lo wa ninu fifun ọmọ ni ọyan, lara wọn si ni pe o le dena iku ọmọ tuntun.
Awọn eroja to wa ninu omi ọyan ni agbara lati dena awọn aarun to le ṣeku pa ọmọde.
Ṣugbọn, o tun lewu fun obinrin to n fun ọmọ lọyan lati ma a mu ọti.
Abẹrẹ ajẹsara
Iwadii imọ ijinlẹ sọ pe awọn ọmọ to ba gba abẹrẹ ajẹsara ni ilana awọn onimọ iṣegun oyinbo ni anfaani ida aadọta pe wọn o le ku ni smọ tuntun. Eyi ko ṣẹyin bi awsn abẹrẹ naa ṣe ma n dena aarun to le ṣeku pa ọmọ.
Ma jẹ ki ooru mu ọmọ tuntun ju
Lootọ ni awọn agbalagba tabi awọn to ti bimọ ri ma n gba iya ọmọ tuntun ni imọran pe ko fi aṣọ bo ọmọ nitori otutu.
Ṣugbọn, ti ooru ba tun pọ ju fun ọmọ tuntun, o le ṣeku pa a.
O dara lati wọ aṣọ fẹlẹfẹlẹ fun ọmọ tuntun lasiko ooru, o si tun le wọ ibọsẹ ati ibọwọ fun. Bakan naa ni ki atẹgun to n wọ inu yaara o si jẹ eyi ti ko tun pọju.
Ifeto sọmọ bibi
Yatọ si pe o lewu fun obinrin lati tete bimọ le ọmọ tuntun, o tun le ni ipa ti ko dara ni ilera ọmọ.
Idi ni pe ti obinrin ba tete loyun le ọmọ, ko ni i ni okun lati tọju ọmọ to wa nilẹ tabi ara rẹ.
Nitori naa ni awọn onimọ ṣe ma sọ pe ki obinrin duro fun bi ọdun kan tabi meji ko to o loyun le ọmọ.
Ọmọ ti ko ti i pe ọdun kan ko gbọdọ jẹ oyin
Kokoro aifojuri to ma n fa 'botulism spores' to wọpọ ninu omi, erupẹ, tabi ounjẹ ti wọn ko ṣe daadaa, ma n wa ninu oyin naa. Nitori naa ni o ko gbọdọ fun ọmọ ti ko ti i pe ọdun kan ni oyin.












