Child Mortality in Nigeria: Ìyanṣẹ́lódì àwọn Nọ́ọ̀sì ṣé àkóbá, ìkókó mẹ́jọ kù níléèwòsàn lalẹ ọjọ́ kàn

Ibanujẹ ti dori awọn abiyamọ kan kodo ni orileede Zimbabwe lẹyin ti awọn ọmọ ikoko mẹjọ ku lalẹ ọjọ kan ni ile iwosan.
Abiyamọ mẹjọ lo wa si ile iwosan lọjọ taa n wi yii, ti wọn si ni lati se iṣẹ abẹ ki wọn ba le bi ọmọ wọn.
Amọ o se ni laanu pe meje ninu awọn ọmọ wọn yii lo ku lalẹ ọjọ kan ṣoṣo.
Ipenija nla ni aisi oṣiṣẹ ilera to to nitori ajakalẹ arun Covid 19 lo ṣokunfa iṣẹlẹ yii.
Gẹgẹ bi awọn Dokita ti ṣe sọ, meji ninu awọn ọmọ yii ni wọn bi ni oku ọmọ nitori pe ko si awọn nọọsi ti yoo gbẹbi awọn awọn nọọsi da iṣẹ silẹ.
Awọn Dokita to ni ki ikọ BBC fi orukọ bo awọn laṣiri sọ pe, mọriwo ni iṣẹlẹ naa jẹ, egungun ṣi n bọ lẹyin nitori pe ko si ipese ohun eelo to yẹ fawọn oṣiṣẹ ilera lati ṣe iṣẹ wọn.
Wọn ni ọpọ ọjọ lawọn alaboyun yii lo lai ri eeyan kankan ti yoo tọju wọn, ki awọn ọmọ wọn to wa ku lasiko ibi.
Ọpọlọpọ awọn ile iwosan ilera lo ti kogba sile ni Harare, ti ṣe olu ilu Zimbabwe nitori iberubojo ajakalẹ Covid-19.
Akọroyin BBC Andrew Harding jabọ pe, Dokita kan sọ fun oun pe, nkan ko rọgbọ ati pe aisi nkan elo idaabo fawọn dokita, oogun fawọn alaisan ati bi iṣẹ ti ṣe wọ awọn dokita lọrun jẹ ipenija nla.
Dokita mii sọ fun pe, iṣẹlẹ yii kii ṣe nkan tuntun, ko ṣẹṣẹ ma waye.














