Iléèwòsàn fi Chiamaka s'áhámọ́ fún ọdún kan nítorí owó

Àkọlé fídíò, Iléèwòsàn fi Chiamaka s'áhámọ́ fún ọdún kan nítorí owó

Ireti gbogbo obinrin to ba ṣẹṣẹ bimọ ni lati kuro nileewosan, ki wọn si pada sile wọn, paapa lati ṣe ayẹyẹ ikomọjade.

Ṣugbọn, ọrọ ko ribẹ fun arabinrin Chiamaka Ogbodo to n gbe nilu Enugu.

Lẹyin ti Chiamaka Ogbodo bimọ tan, ireti ayọ lo wa ni ọkan rẹ pe oun yoo lọ sile lati ṣe ajọyọ ọmọ tuntun naa, ṣugbọn ọdun kan gbako lo lo ni ile iwosan ki o to fi oju kanle.

Awọn alaṣẹ ile iwosan naa to wa ni ilu Enugu ko tu u silẹ ko lọ sile nitori airi owo itọju rẹ san pe.

Koda, wọn ko jẹ ki o yọju si ibi oku baba rẹ lasiko naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: