Chrisland Pupil Sexual Scandal: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa kìí ṣe àṣemáṣe

Oríṣun àwòrán, Chrisland School
Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Èkó tí ránṣẹ́ pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ọmọdé èyí tí wọ́n fi kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Chrisland tó wà ní agbègbè Victoria Garden City, ìpínlẹ̀ Eko.
Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹrin, ọdún 2022 wí pé gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ọmọ ọdún mẹ́wàá, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìwé kẹfà ni ilé ẹ̀kọ́ Chrisland ní àwọn tí darí láti lọ wí tẹnu wọn ní ẹ̀ka to ń mójútó ìwà ọ̀daràn tó wà ní Panti.
Nígbà tó ń sọ ibi tí ìwádìí dé dúró lórí ọ̀rọ̀ náà, Hundeyin ní àwọn ti ní kí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kan kọ gbogbo ohun tí wọ́n bá mọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
- Bí mo ṣe rí iṣẹ́ ní UK rèé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú - Ọmọ Naijiria sọ ìrírí rẹ̀
- Ǹkan tí a mọ̀ rèé nípa ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland
- Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹrín etí rí, kí n tó leè ṣe àwo orin - Tope Alabi
- Ọlọ́run ló sọ fún mi kí n lọ dupò ààrẹ Naijiria ní 2023, ohun tó sọ fún mi rèé - Ìmàámù Afeez Akinola
- Ìjọba fìdíhẹẹ́ ló yẹ ká kéde lẹ́yìn sáà Buhari, Ìwé òfin Nàìjíríà kò kájúẹ̀ - Afe Babalola
- Kọjú sí iṣẹ́ ìwàásù táa fí rán ọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wà darapọ̀ mọ́ òṣèlú - Ilééṣé ààrẹ sí Father Kukah
- Àwọn adigunjalè já wọ ilé ounjẹ lọ́jọ́ ọdún Ajínde, wo ọṣẹ́ tí wọ́n ṣe
- Nítorí orin 'Angeli mi' ti Tope Alabi kọ, iléeṣẹ́ MTN, Glo àti Airtel dèrò ilé ẹjọ́
- Nítorí orin 'Angeli mi' ti Tope Alabi kọ, iléeṣẹ́ MTN, Glo àti Airtel dèrò ilé ẹjọ́
Bákan náà ló ní lẹ́yìn èyí ni ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yóò bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.
Ó ṣàlàyé pé lára àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kan ni olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ Chrisland, G. I. Azike àti àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn wí pé wọ́n ṣe àṣemáṣe pẹ̀lú ọmọ àwon lásìkò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún lọ kópa níbi ètò eré ìdárayá àwọn ilé ẹ̀kọ́ káàkiri àgbáyé.
Ní ìlú Dubai, orílẹ̀ èdè United Arab Emirates ní ìdíje náà ti wáyé nínú oṣù kẹta ọdún 2022.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹrin ni ìyá akẹ́kọ̀ọ́ náà fi fọ́nrán kan léde níbi tó ti fẹ̀sùn kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Chrisland kan wí pé wọ́n fún ọmọ òun ní oògùn olóró mú, tí wọ́n sì fi ipá bá lòpọ̀.
Fọ́nrán ọ̀hún sì ti ń fà awuyewuye láàárín àwọn ènìyàn lórí ayélujára.
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó náà sì ti gbé ilé ẹ̀kọ́ náà tì pa fún ìgbà díẹ̀ náà nítorí ẹ̀sùn náà.
Kí ni ilé ẹ̀kọ́ Chrisland sọ?
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Akin Fadeyi, ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ Aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ Chrisland fi síta lórúkọ ilé ẹ̀kọ́ náà sọ wí pé lóòótọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ náà wà lára akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́rin tí àwọn kó lọ sí ìlú Dubai láti kópa níbi eré ìdárayá nínú oṣù kẹta ọdún yìí.
Fadeyi ni ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí ìyá ọmọ náà fi kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kìí se òtítọ́.
Ó ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún nínú gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn kó lọ sí Dubai àti wí pé ọmọbìnrin náà lọ ṣáájú ìwà àṣemáṣe ọ̀hún.
Ó fi kún wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kópa nínú ìdíje "Truth or Dare" lẹ́yìn tí àwọn tí àwọn ti paná pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ sùn.
Ó ní èyí ló ṣokùnfà ìdí tí àwọn fi ní kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ rọ́kún nílé fún ìgbà kan ná.















