APC withdrawal letter: Awuyewuye lórí ìwé mó yọ ọwọ́ tàwọn olùdíje gbọdọ̀ fọwọ́ sí, kí ló lè tẹ̀yìn rẹ̀ wá?

Aworan ami idanimọ APC ati iwe ''withdrawal letter''

Oríṣun àwòrán, APC Nigeria

Nilẹ oni to mọ laarin agbami awọn to n gbero lati du ipo kan tabi omiran inu ẹgbẹ oṣelu APC, iwe kan to wa lara fọọmu erongba mo fẹ dupo wọn ti n da iporuru ọkan silẹ.

Iwe taa n wi yi,Form 18, sọ pe ẹni ti ko ba fẹ du ipo mọ gbọdọ buwọlu iwe naa pe oun yoo fi tọkan tọkan yọwọ kuro ninu idije ipo naa.

Lede oloyinbo iwe yi ni akọle ti wọn pe ni ''Withdrawal letter'' ti aworan rẹ si ti gba oju opo ayelujara kaakiri.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo àgbáyé kódà America ló ń bọ̀ wá sí Omuo-Ekiti láti wá forí balẹ̀ ní Ààfin ńlá tí yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run'

Lati le mọ ohun ti iwe yi tunmọ si BBC gbiyanju lati kan si awọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ ni paapa akọwe ipolongo ẹgbẹ tii ṣe amofin,Felix Morka.

A tun ba agbẹjọro kan sọrọ lori ọrọ yi.

Ẹgbẹ APC ko mu iwe yi ni dandan fun oludije kankan

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu akọwe ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC, Felix Morka, o ni iwe yi wa lara awọn eronja ti oludije a maa gba bo ba ti sanwo fọọmu tan.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni iwe ofin idibo Naijria,Electoral Act, abala to sọ nipa bi ẹgbẹ oṣelu ṣe le yan oludije sipo lo faaye silẹ fun iwe mo yọwọ, mi o ṣe mọ yi.

O ni fọọmu naa wa pẹlu awọn fọọmu mi ti oludije ẹgbẹ gba lọdọ awọn ṣugbọn kii ṣe dandan fun oludije lati buwọlu bi ko ba fẹ.

Aworan iwe mo yọwọ mi o ṣe mọ APC

Oríṣun àwòrán, APC

''Abala to de ọrọ idibo abẹle lo ni ka pese ọna ti oludije yoo fi finu fẹdọ sọ ti ko ba fẹ kopa ninu idibo fun ipo kankan mọ.''

''Iwe yi ni ọna to le fi sọ fun ẹgbẹ ni igba to ba wu pe oun ko lero lati du ipo to ti ṣaaju sọ tẹlẹ.Kii ṣe dandan ki oludije buwọlu ti ko ba ni erongba lati yọwọ ninu idije''

O tẹsiwaju pe awọn naa fi iwe naa silẹ lati le jẹ ki eto tubi n nubi ẹgbẹ lọ ni irọwọ rọsẹ bi wọn ba ṣetan lati ṣe idunadura lori ipo taa mọ si ''consensus''

O ni awọn ko mu ọmọ ẹgbẹ ni dandan lati buwọlu ati pe ilana ofin idibo lawọn n tẹle lori ọrọ to wa nilẹ yi.

Ki lawọn amofin miran sọ nipa fọọmu yi

BBC Yoruba ba agbẹjọro Kunle Solihu Adebayo to fi ilu Ibadan ṣe ibujoko sọrọ nipa iwe yi ati pe ṣe ko lewu fun oludije.

O ni lẹnu iwọn toun m nipa bawọn ẹgbẹ oṣelu ṣe n ṣeto idibo abẹlẹ lati le fi yan ọmọ ẹgbẹ ti yoo dije ipo, iru nkan bayi ko tako ilana ẹgbẹ.

O ni lopin igba ti wọn ko ba ti mu ọmọ ẹgbẹ ni dandan lati buwọlu iwe naa, ''kii ṣe nkan to lewu fun ọmọ ẹgbẹ''

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

'' Lọpọ igba lawọn ẹgbẹ oṣelu a maa fikun lukun lori ipo pipin ati yiyan oludije ẹgbẹ, iru fọọmu yi wa lati jẹ ki awọn to ba fẹ juwọ silẹ fun ipo kan ri ọna gbe gba''

''Ti wọn ko ba ti mu awọn ọmọ ẹgbẹ ni dandan lati buwọlu fọọmu,ti a ko si ri ibi ti wọn kọ si pe ki wọn buwọlu ni dandan, ko si nkan to buru nibẹ''

O tẹsiwaju pe ọpọ ẹgbẹ naa lo maa n faye silẹ fawọn to ba fẹ jawọ kuro ninuidije ti wọn a si ni nkan miran ti wọn yoo fi paarọ fun iru eeyan bẹ.