Iléẹjọ́ ní kí Trinity Guy tún padà wá ní oṣù kẹjọ, ìdí rèé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ile ẹjọ magisireeti to n gbọ ọrọ to ni ṣe pẹlu ẹtọ ọmọde nipinlẹ Oyo, ti sun igbejọ gbajugbaja adẹrinpoṣonu Abdullahi Maruff ti ọpọ eeyan mo si Trinity Guy, Ahmed Isiaka ati Ahmed Rofiat siwaju.

Ile ẹjọ gbe igbesẹ yii nitori aisi iwe ẹsun eyi ti wọn fi pe wọn lẹjọ.

Ọjọ kẹta oṣu kẹjọ ọdun yii ni igbejọ naa yoo waye niluu Ibadan.

Saaju ni adajọ Magisireeti P.O Adetuyibi to n gbo ẹjọ naa paṣẹ pe ki wọn gbe adẹrinpoṣonu ọhun ati awọn obi ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹwa naa lọ si atimọle titi ti igbejọ yoo fi waye lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Bo tilẹ jẹ wi pe agbẹjọro fun Abdullahi Maruff ti gbogbo eeyan mo si Trinity Guy, Oludare Olubayo ati A.O Alabi ẹni to n ṣoju awọn obi ọmọdebinrin naa, rọ ile ẹjọ lati ni suuru ki iwe ipejọ ti wọn n reti de.

Ninu ọrọ rẹ magisireeti P.O Adetuyibi ṣalaye wi pe ile ẹjọ ko le duro de ẹni ti o ṣẹṣẹ ko mu iwe ipejọ wa.

O ṣalaye siwaju wi pe o ṣee ṣe ki awọn ẹsun ti wọn fi kan Adẹrinpoṣonu Abdullahi Maruff dinku sii.

O wa kesi agbẹjọro Abdullahi Maruff lati jẹ ki gbogbo iwe ipejọ ati awọn ohun elo ti wọn yoo nilo fun ipejọ naa wa ni arowoto ṣaaju igbejọ eyi ti yoo waye ni ọjọ kẹta oṣu kẹjọ ọdun yii.

Trinity Guy wọ gau lẹyin ti fidio kan jade sori ayelujara nibi to ti n beere ọrọ lọwọ ọmọdebinrin kan nipa nnkan ọmọkunrin tirẹ.

Trinity Guy ti dé ilé ẹjọ́ lónìí, wo ohun tí yóò ṣẹ̀lẹ̀ ní kíkún níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀

Aworan Aderinposonu Abdullahi Maruf

Oríṣun àwòrán, Oyo State Police Twitter

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbejọ lori ẹsun ti wọn fi kan adẹrinposonu nni, Abdullahi Maruff ti ọpọ eeyan mọ si Trinity Guy tẹsiwaju lọjọ Iṣẹgun.

Ile ẹjọ to n risi ọrọ idile ni o n dari igbejọ naa lori ẹsun pe Abdullahi Maruf hu iwa itabuku ọmọdebinrin kan nipa alufansa ọrọ ibalopọ to sọ sii ninu fidio rẹ kan.

Ninu fidio ọhun ni Trinity Guy ti n beere ọrọ lọwọ ọmọdebinrin kan nipa nnkan ọmọkunrin tirẹ.

Lara awọn to wa si ile ẹjọ naa ni awọn aṣoju ẹka to n risi ẹsun hihu iwa ipa si ọmọde nipinlẹ Oyo.

A tun gbọ pe awọn obi ọmọdebinrin yii naa wa lara awọn to peju si ile ẹjọ.

Idi tawọn obi rẹ naa fi wa ni ile ẹjọ ni pe adajọ sọ lasiko ijoko to ṣaaju wi pe wọn lẹjọ lati jẹ lori iṣẹlẹ yii.

Gẹgẹ bi akọroyin wa ṣe jabọ, ile ẹjọ Majisireeti sọ pe ki wọn lọ gba atẹgun lọgba ẹwọn pẹlu Trinity titi di igba ti igbẹjọ yoo fi tẹsiwaju.

Ahmed, ẹni ogoji ọdun to jẹ baba rẹ, ati Rofiat, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni wọn fẹsun kan pe wọn fọwọsowọpọ pẹlu Trinity Guy lati gbe igbesẹ to lodi sofin lilo ọmọde lori ayelujara.

Adajọ P.O Adetuyibi ni ko tẹwọgba anfani lati ma jẹjọ fun awọn olujẹyọ ọhun, to si ni ki wọn lo maa gba atẹgun lọgba ẹwọn Agodi titi ẹjọ naa yoo fi ni ojutu.

Bawo lọrọ ṣe de ibi to de yi?

Ni oṣu Kẹfa ọdun yi ni ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni ipinlẹ Oyo fiwe pe adẹrinposonu oni ''prank'' yi lati wa dahun si awọn ibeere kan ni agọ wọn.

O ṣe ipade naa pẹlu igbakeji Kọmisana ọlọpaa ti o si ṣalaye awọn ọrọ kan fun awọn agbofinro.

Abalọ ababọ ni pe alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Oṣifẹsọ fi atẹjade sita to si ni awọn ti lọ fi ṣinkun ofin mu baba ati iya ọmọ naa, Isiaka Ahmed ati aya rẹ Rofiat.

Gẹgẹbi o ṣe sọ, Trinity guy ṣalaye fun awọn ọlọpaa to fi ọrọ wa a lẹnu wo pe, oun gba aṣẹ lọwọ awọn obi ọmọdebinrin naa ki oun to lo o fun fidio naa, ati ki oun to gbe e si ori ayelujara.

Ninu ifọrọwerọ to wa ṣe pẹlu BBC News Yoruba, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ naa sọ pe gbajumọ alawada oriayelujara naa, sọ pe oṣu kọkanla ọdun 2022 ni oun fi fido naa sita.

O ni ko pẹ pupọ ti oun gbe fidio naa sita ti oun tun yọọ kuro nigba ti ariwo dide tako o paapaa lori iwa aitọ rẹ pẹlu ọrọ ọmọde.

Ṣaaju eyi yii ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ọga Ọlọpaa Olumuyiwa Adejọbi ti kọkọ ke si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ pe ki wọn ti ọwọ Trinity guy bọṣọ pẹlu ọkan o jọkan fidio idaya jani to n ṣe eyi to sọ pe o lodi si ẹtọ ọmọniyan ati alafia ilu