'Ó sàn kí n f'owó Hajj mi ọdún yìí pèsè oúnjẹ fáwọn aláìní ju kí n lọ sí Mecca lọ'

Aworan musulumi ni Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ awọn musulumi to fẹ rinrin ajo lọ si Hajj lọdun yii lati orilẹede Naijiria lo ti n kọminu pe bo ya lo maa ṣeeṣe mọ, lẹyin ti ajọ NAHCON to n ri si irinajo lọ si Hajj tun fowo kun owo irinajo lọ si Mecca fun ọdun 2024 pẹlu owo to din diẹ ni milọnu meji naira.

Igba keji niyii ti ajọ NAHCON yoo kede afikun owo hajj, eyi to jẹ ko nira bayii fun ọpọ ọmọ Naijiria ti wọn fẹ lọ hajj lọdun yii.

Bakan naa, ọpọ gbagbọ pe gbedeke ọjọ mẹrin ti ajọ naa fawọn to fẹ rinrin ajo lọ sí Mecca lati san N1.9m to jẹ afikun owo irinajo ọhun ko ni jẹ ko rọrun fun ọpọ eeyan lati lọ mọ.

Ọkunrin kan to fẹ rinrin ajo lọ sí Hajj lọdun yii sọ fun BBC pe oun ti pinu lati lo owo irinajo Hajj oun pese ounjẹ fawọn alaini ni awujọ oun.

Ọkunrin naa sọ pe imọran awọn onimọ nipa ẹṣin musulumi ni oun tẹle lati ṣe bẹẹ.

Ọkunrin naa ni "pẹlu ọwọngogo to gbode ni Naijiria bayii, a ni lati ṣe iranwọ ounjẹ fawọn alaini."

"Ẹ fun wa lowo wa, a o lọ si Hajj mọ"

Ọpọ eeyan kaakiri agbaye ni owo ti wọn san fun irinajo lọ si Hajj ọdun yii pọju, latari bi ọrọaje awọn orilẹede ti n ṣojojo lẹyin ti ajakalẹ arun covid-19 ṣọṣẹ kari aye.

Amọ, awọn orilẹ-ede ilẹ Africa ni o pa lara julọ.

Awọn arinrin-ajo lọ sí Mecca lati Naijiria ati Ghana lo ni ipenija yii ju latari bi owo naira ati cedis ko ṣe gbewọn mọ si dọla.

Ajọ to n ri si irinajo lọ si Hajj ṣalaye pe eeyan 49,000 lo ti sanwo ninu 75,000 to yẹ ko ti sanwo fun irinajo naa.

"Igba keji ree ti wọn maa fowo kun owo Hajj.

Lakọkọ, wọn fi miliọnu kan naira kun un, a si san owo naa.

Ṣadeede ni wọn tun ṣe afikun owo to to miliọnu meji naira.

Nibo ni a ti fẹ ri owo naa?" Ọkunrin kan lara awọn arinrin-ajo lo sọ bẹẹ.

Ọkunrin naa fikun un pe "ọpọ awa ti a ti sanwo fun Hajj ọdun yii ni a ti beere owo wa pada."

Obinrin kan to ba BBC sọrọ lori foonu naa fi aidunnu rẹ han si afikun owo irinajo Hajj.

Obinrin naa sọ pe "gbedeke ti wọn fun wa ti kere ju.

Ti o ba wu Ọlọrun ki n lọ Hajj lọdun yii, mo maa lọ.

Ti ko ba ṣi ṣeeṣe, ko si iyọnu."

NAHCON fowó kún owó ìrìnàjò Hajj, ó tún fún àwọn arìnrìnàjò ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́rin

Aworan Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n ri si irinajo lọ si Hajj lorilẹede Naijiria, NAHCON ti fowo kun owo irinajo lọ si Mecca fun ọdun 2024 pẹlu owo to din diẹ ni milọnu meji naira, N1, 918,032,91.

Eyi lo wa ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa, Fatima Sanda Usara gbe sita lọjọ Aiku.

Bakan naa ni ajọ naa tun fun awọn arinrinajo ni gbedeke lati san owo naa di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024.

Ajọ NAHCON ni igbesẹ yii ko sẹyin bi kudiẹkudiẹ ṣe ba owo naira si owo dọla lorilẹede Naijiria.

Saaju ni NAHCON kede pe owo irinajo fun Hajj 2024 yoo jẹ́ N4.9m sugbọn wọn ti ṣe atunṣe si igbesẹ naa ti wọn si n rọ awọn to ti san owo tẹlẹ lati fi owo toto N1.9m kun owo ti wọn ti san, eyi ti apapọ rẹ̀ jẹ N6.8m.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atẹjade naa, NAHCON ni awọn kan saara si awọn araalu fun suuru ti wọn nipẹlu ajọ naa, ti ajọ naa yo si ri daju pe irinajo naa jẹ aṣeyọri.

NAHCON ni o ṣe koko fun awọn lati sọ fun awọn eeyan to n gbero lati rin irinajo lori owo baalu ti yo gbe wọn ati awọn nnkan mii.

“Owo Naira si dọla jẹ N897 ninu oṣu Kejila ọdun to kọja sugbọn nnkan ko ri bẹ mọ, ti owo dọla si ti gbe owo lori bayii.

“Iroyin ayọ bẹẹ ni pe ni pe pẹlu bi owo naira si dọla ṣe jẹ 1,474 bayii, ajọ NAHCON gbe igbesẹ lati pe ijọba lati dasi ọrọ nipa irinajo naa, ti wọn ni lati fi owo toto N1,918,032 kun owo irinajo.

“Awọn arinrinajo ti wọn ba si fẹ kopa ninu Hajj 2024 ni a rọ lati san owo yii, o pẹ ju ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta nitori ko ni si anfaani lati san owo mọ,

“Bakan naa, awọn to sẹsẹ fẹ fi orukọ silẹ yoo san owo toto N8,226,464.74 fun awọn apa ariwa, ti awọn to wa lati guusu yoo san N8.454.464.74.”

Ajọ baa gba awọn arinrinjo to ba fẹ gba owo wọn pada lati kan si igbimọ Hajji ipinlẹ wọn.