Àgbà òṣèré, Amaechi Muonagor jáde l’áyé

AMAECHI MUONAGOR

Oríṣun àwòrán, AMAECHI MUONAGOR/INSTAGRAM

Agba oṣerekunrin, Amaechi Muonagor, ti ku.

Ibatan rẹ kan, Tony Muonagor ti ọpọ mọ si Tony Oneweek, lo fidi iku rẹ mulẹ fun BBC.

Ẹni ọdun mkanlelọgọta ni ko to o ku lẹyin ti aisan kindinrin, itọ ṣuga ati rọpa-rọsẹ, ba a finra.

Lọdun 2023 ni aisan rọpa-rọsẹ kọluu, eyi to mu ki ẹsẹ osi rẹ rọ.

Ogbontarigi oiṣere naa ku lẹyin ọjọ diẹ to ke gbajare lori ayelujara pe ki awọn ọmọ Naijiria dide iranlọwọ owo fun un lati tọju ara rẹ, paapaa ko le ri owo san fun gbigba kindinrin miran.

Ibẹrẹ oṣu Kẹta ni fidio nkan jade si ori ayelujara, eyi to ṣafihan osẹre naa lori idubulẹ aisan, ti ko si le sọrọ daadaa.

Oṣere miran to joko ti i, lo n sọ ninu fidio naa pe Ọgbẹni Muonagor nilo iranlọwọ owo.

Iroyin iku rẹ jade lẹyin ọsẹ diẹ ti osẹre Yoruba, Sisi Quadri ati agba osẹre miran, John Okafor ‘Mr Ibu’, jade laye.

Ọmọbibi ipinlẹ Anambra ni Oloogbe Muonagor.

Lọdun 1989 lo kọkọ bẹrẹ iṣẹ ni ileeṣẹ akoroyinjọ ni Naijiria, News Agebcy of Nigeria, lẹyin to pari eto agunbanirọ.

Lẹyin ọdun diẹ lo fi iṣẹ naa silẹ, to si di oṣere tiata.

O gbajumọ fun ọpọlọpọ ere, paapaa awọn ere apanilẹrin, to ṣe.