Kínni ó ń jẹ́ kí ojú-ọjọ́ máa gbóná káàkiri àgbáyé?

Aworan aye lati oke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ nnkan tawọn eeyan n ṣe lo n jẹ ki ooru apọju maa mu, koda, awọn nnkan yii tun n jẹ ki omi okun maa ru si.

Apẹẹrẹ si wa wi pe nnkan tun le buru si lawọn ọdun to n bọ, amọ, awọn onimọ sayẹnsi ti sọ pe awọn igbesẹ ni kiakia le dẹkun ipa ti eyi le ni lori aye.

Kinni wọn n pe ni ayipada oju-ọjọ?

Ayipada oju-ọjọ tumọ si bi oju-ọjọ ṣe maa n yi pada ti yoo si maa n gbona, eyi naa maa n fa ooru amuju.

Ni bii ọdun mẹwaa sẹyin bayii, aye ti gbona ju ti atẹyinwa lọ pẹlu iwọn 1.2C.

Akọsilẹ ti fihan pe aye gbona sii pẹlu iwọn1.5C laarin oṣu mejila bẹrẹ lati oṣu Keji ọdun 2023 si oṣu Kinni ọdun 2024.

Ayipada oju ọjọ maa n ṣelẹ pẹlu awọn nnkan tawọn eeyan n ṣe eleyii to ṣokunfa rẹ.

Aworan girafu to n ṣafihan bi aye ṣe gbona lọdun 2023

Bawo lawọn eeyan ṣe n fa ayipada oju-ọjọ?

Oju-ọjọ ti maa n yi pada lati ọjọ to ti pẹ ati lati igba ti aye ti wa.

El Nino eyi to tumọ si bi oju-ọjọ ṣe maa n yi pada ninu okun le ṣokunfa ayipada oju ọjọ, amọ, fun asiko diẹ ni iru eyi le ṣẹlẹ gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ lọdun 2023.

Amọ, iru nnkan yii kọ ni o ṣe okunfa iru ayipada oju-ọjọ to ti n ṣẹlẹ laye laarin ọgọrun ọdun sẹyin bayii, gẹgẹ bi IPCC to jẹ igbimọ to n ri si ọrọ oju-ọjọ labẹ ajọ iṣọkan agbaye, UN ṣe sọ.

Ajọ IPCC ni awọn nnkan tawọn ọmọ eeyan n ṣe bi eedu, wiwa epo rọbi ati afẹfẹ gaasi lo n fa ayipada oju-ọjọ.

Nigba kugba tawọn eefin epo ba ti tu sinu afẹfẹ, eroja oloro CO2 ni o maa n tu sinu afẹfẹ.

Ara eroja oloro yii wa lara nnkan ti o maa n jẹ ki aye gbona.

Eroja oloro CO2 ti pọ sii ni iwọn ida aadọta ninu ọgọrun lati igba tawọn eeyan ti bẹrẹ si ni fọ epo.

Eroja oloro CO2 maa n tu oriṣiiriṣii kẹmika to le ṣakoba sinu afẹfẹ.

Aworan to n ṣafihan eroja oloro CO2 loju ọrun

Akoba wo ni ayipada oju-ọjọ ti ṣe bayii?

Bi iyatọ ṣe n ba oju-ọjọ pẹlu iwọn1.2C ni bii ọdun mẹwaa sẹyin le maa pọju.

Amọ, o ni ipa nla lo ri ayika ati:

  • bi ooru amuju ṣe n mu to fi mọ ojo nla nla to n rọ.
  • bi omi okun ṣe n ru sii ni gbogbo igba.
  • bi adinku ṣe ba yinyin inu okun.
  • bi okun ṣe n gbona.

Iyatọ n ba aye awọn eeyan.

Fun apẹẹrẹ, awọn apa ẹkun ila oorun ilẹ Africa ni iriri airọ ojo to buru julọ fun ogoji ọdun, eyi to jẹ ki iyan ounjẹ ba ogun miliọnu eeyan finra.

Lọdun 2022, ooru amuju nilẹ Yuroopu ṣokunfa iku ọpọ eeyan.

Kilode ti gbigbona oju-ọjọ pẹlu iwọn 1.5C ṣe ṣe pataki ati pe ipa wo ni ayipada oju-ọjọ yoo ni lori aye?

Bi oju-ọjọ ba ṣe n gbona si ni o maa n ni ipa to lagbara lori aye.

O ṣe pataki ki bi oju-ọjọ ṣe n gbona ma ju iwọn 1.5C lọ gẹgẹ bi ajọ IPCC ṣe sọ.

Awọn onimọ sayẹnsi ko le fidi rẹ mulẹ tan patapata, amọ ipa ti gbigbona oju-ọjọ pẹlu iwọn 1.5C si 2C maa ni iwọnyii:

  • Oju-ọjọ yoo maa gbona lawọn ọjọ kan pẹlu iwọn 4C si 3C.
  • Riru omi okun sii pẹlu iwọn mita 0.1, eyi to n fa iṣẹlẹ ẹkun-omi fun awọn eeyan to to miliọnu mẹwaa.
  • Gbogbo awọn okuta isalẹ okun ni yoo di ohun igbagbe.
  • Ọpọ awọn igi oko ati awọn ẹranko ti wọn ni eegun lara ni ko ni gbadun.
  • Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan ni o le di otoṣi nipa akoba ti ayipada oju-ọjọ yoo ṣe fun wọn ki o ti di ọdun 2050.

Ipe ti n wa lati ma jẹ ki oju-ọjọ maa gbona ju iwọn 1.5C lọ ki o maa ba yiwọ.

Ti o ba le ju iwọn 1.5C lọ, yoo sẹ akoba fun ọpọlọpọ nnkan.

Aworan bi oju-ọjọ ṣe maa n gbona niyii lori aye

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi oju-ọjọ ṣe maa n gbona niyii lori aye

Gẹgẹ bi ajọ IPCC ṣe sọ, eeyan to le ni biliọnu mẹta ati aabọ ni ayipada oju-ọjọ maa n ṣakoba fun laye.

Awọn kan to wa ninu wọn ti wọn n gbe lawọn orilẹede ti wọn ko rọwọ họri lo maa jiya ju.

Eyi gan an lo jẹ kawọn eeyan maa kọminu nipa awọn eeyan ti ayipada oju-ọjọ n ṣakoba fun tori awọn orilẹede nla lo n ṣe eyi ti pọju ninu ohun to n fa ayipada oju-ọjọ.

Gbogbo aye lo fori fa ipa ayipada oju-ọjọ.

Fun apẹẹrẹ, ayipada oju-ọjọ to ṣakoba fun ere oko le fa ọwọngogo ounjẹ lagbaaye.

Kinni awọn ijọba orilẹede agbaye n ṣe nipa ayipada oju-ọjọ?

Ninu iwe adehun ti ọrilẹede bii igba fọwọ si niluu Paris lọdun 2015, wọn ṣeleri lati ma jẹ ki oju-ọjọ gbona ju iwọn 1.5C lọ.

Lati le ṣe eleyi, akitiyan gbọdọ wa ti yoo jẹ ki eroja oloro CO2 poora titi ọdun 2050.

Eleyii tumọ si pe adinku nla gbọdọ ba gbogbo nnkan tawọn eeyan n ṣe to maa n tu eroja oloro CO2 sinu afẹfẹ.

Ọpọ orilẹede lo n ṣiṣẹ tọ ipinnu yii.

Amọ, awọn nnkan yii ṣi tun n ṣẹlẹ ati pe idaniloju wa pe oju-ọjọ ṣi maa gbona ju iwọn 1.5C lọ gẹgẹ bi ajọ IPCC ṣe sọ.

Aworan to n ṣafihan bi aye sẹ n sun mọ bi oju-ọjọ ko sẹ ni ju 1.5C lọ

Amọ, ilọsiwaju ti wa lawọn ibi kan, awọn ileeṣẹ to n ṣe ọkọ ti yoo maa lo ina yatọ fun epo.

Awọn olori orilẹede n ṣe ipade pọ lọdọọdun lati jiroro lori ayipada oju-ọjọ.

Apero ajọ iṣọkan agbaye, UN lori ayipada oju-ọjọ to waye kẹyin ni eyi ti orilẹede UAE gbalejo rẹ ti wọn pe akori rẹ ni COP28.

Fun igba akọkọ, awọn orilẹede agbaye fẹnu ko lati dẹkun eefin epo rọbi to n ṣakoba fun oju-ọjọ.

Ninu oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii ni apero ajọ UN mii yoo tun waye lorilẹede Azerbaijan.

Kinni awọn eeyan le ṣe nipa ayipada oju-ọjọ?

Ijọba atawọn ileeṣẹ nla nla ni wọn niṣẹ to pọ ju lati ṣe, amọ, awọn araalu naa le ṣe iranwọ nipa:

  • ṣiṣe adinku wiwọ ọkọ ofurufu
  • lilo epo tabi afẹfẹ gaasi
  • lilo afẹfẹ gaasi idana nile
  • lilo ọkọ to n lo ina mọnamọna
  • lilo ẹrọ amulegbona to n lo ina mọnamọna lasiko otutu
  • ṣiṣe adinku jijẹ ẹran ẹlẹjẹ