Wo ọkùnrin tó gbé ilé ayé fún ọdún méjìdínlọ́gọ́rin(78) pẹ̀lú ẹ̀dọ̀fóró onírin

Aworan Paul Alexander

Oríṣun àwòrán, Gofundme

Ọmọ ọdun mẹfa ni Paul Alexander nigba ti o ṣadeedee ba ara rẹ ninu irin, eyi ti ori rẹ nikan yọ sita.

Ko tiẹ mọ ọ lara wi pe oun wa ninu irin kan, bẹẹni ko le sọrọ nigba ti o gbiyanju lati pariwo fun iranlọwọ.

Arun rọmọlapa-rọmọlẹsẹ lo sọ Paul di ẹni ti ko le da ara rẹ gbe mọ.

Koda, ko le da mi fun ra rẹ mọ lai lo ẹdọforo onirin ti wọn gbe si i lara, lẹyìn ti wọn ṣe iṣẹ abẹ fun un.

Paul ni ẹni to pẹ laye julọ pẹlu ẹdọforo onirin ninu iwe itan agbaye, lẹyin ti o ku laipẹ yii lẹni ọdun mejidinlọgọrin.

Iru igbe aye wo ni Paul gbe pẹlu ẹdọforo onirin?

Awọn ọmọde mii t'awọn naa ni aisan rọparọsẹ wa pẹlu Paul nile iwosan lọdun 1952 ni Texas lorilẹede America.

Lẹyin ti Paul ti lo ọdun meji nile iwosan, awọn dokita bẹrẹ si ni kọminu lori bi ọjọ iwaju rẹ yoo ṣe ri pẹlu ẹdọforo onirin lara rẹ.

Bayii l'awọn obi rẹ gbe e lọ si ile pẹlu ero wi pe o le ma pẹ ti yoo jade laye.

Amọ, niṣe ni ọjọ n gori ọjọ ti ọdun si n gori ọdun, Paul ko si ku o.

Ina ẹlẹntiriki ni ẹdọforo onirin yii n lo.

Amọ, ọwọ ni wọn maa fi n yi i ti wọn ba ti mu ina lọ.

Koda, awọn alabagbe awọn obi Paul maa n ṣe iranwọ lati fi ọwọ yi ẹrọ ẹdọforo yii ti ina ba ti lọ.

Philip to jẹ aburo Paul sọ fun BBC pe ileri ti awọn obi Paul ṣe ni wi pe, awọn yoo ra ọmọ aja to rẹwa fun un lo jẹ ko ni igboya lati maa mi fun ra rẹ.

Nigba to bẹrẹ si ni mi fun ra rẹ diẹ diẹ lo bẹrẹ si maa gbe igbe aye gidi.

Igba yẹn lo bẹrẹ si ni ṣere pẹlu awọn ọrẹ rẹ ni adugbo lori kẹkẹ alailera rẹ.

Nigba ti o ba rẹ ẹ ni yoo pada sinu ẹdọforo onirin rẹ.

"Paul ko yatọ si awọn eeyan mii si mi, ẹgbọn mi ni.

A maa n ja, a maa n ṣere papọ, a maa n lọ sibi ayẹyẹ papọ," Phillip lo sọ bẹẹ.

Paul kẹkọọ gboye nile ẹkọ giga

Paul bẹrẹ ile ẹkọ nile awọn obi rẹ.

Koda, o tun kẹkọọ gboye imọ nipa ofin eyi to fi di agbẹjọro.

Philip sọ pe "awọn obi awọn ni wọn kọkọ n ran Paul lọwọ pẹlu ẹdọforo onirin rẹ nigba to wọ ile ẹkọ fasiti Texas.

Nigba to ya, wọn gba olutọju kan fun un.

Ṣadeedee ni olutọju naa ko wa mọ.

Oriṣiiriiṣi eeyan lo n ṣe iranwọ fun Paul ni ilegbe awọn akẹkọọ to n gbe.

Wọn maa n ba a ti kẹkẹ rẹ kaakiri ọgba ile ẹkọ naa."

Paul pari ẹkọ rẹ, o si ṣiṣẹ gẹgẹ bi amofin ni Dallas.

"Iyalẹnu lo maa n jẹ fawọn onibara rẹ ti wọn ba ri ninu ẹdọ-foro onirin.

Ọpọ eeyan lo maa n kọ ha ti wọn ba ti ri i," Philip lo sọ bẹẹ.

Aworan Paul Alexander

Oríṣun àwòrán, Rotary Club of Park Cities Dallas

Orukọ Paul wọ inu iwe itan Guiness World Records

Ni ọdun 2023, ni Paul wọ inu iwe itan Guiness World Records gẹgẹ bi ẹni ti o lo ẹdọforo onirin fun igba to pẹ julọ laye.

Aburo rẹ, Philip nifẹ rẹ gan an, o ṣi maa n ṣe afẹri rẹ.

"Mo ri i gẹgẹ bi ẹni to ni oriṣiriṣi idojukọ laye.

Mo maa ṣe afẹri Paul gan an.

Oun ni mo maa n pe lasiko ti mo ba ti ni iṣoro," Philip ranti Paul.

O ni o le maa ya ọpọ eeyan lẹnu lagbaaye pe Paul dagba ko to ku pẹlu ẹdọforo onirin, amọ, Philip ni ko le ya awon obi awọn lẹnu.

Philip sọ pe "wọn ni igbagbọ ninu Paul.

Wọn si fi ifẹ han si i, tori naa, ko le ya wọn lẹnu wi pe o dagba ki o to jade laye."