Wo bí o ṣe le fi ìmọ́tótó dènà ewu tó le bá nǹkan ọmọkùnrin rẹ

Ọkunrin to n yẹ abẹ rẹ wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

To ba jẹ pe ọkunrin ni ọ, ọkan lara awọn ẹya ara to ṣe pataki lara rẹ ni nnkan ọmọkunrin rẹ, eyi ti wọn n pe ni ‘penis' ni ede Gẹẹsi.

Nnkan ọmọkunrin jẹ irinṣẹ ibalopọ fọkunrin, nigba ti ọmọkunrin ba si ti n bàlágà lo maa n tobi si i ti yoo si bẹrẹ si i ni atọ ninu.

Yatọ si pe ẹya ara yii ni ọkunrin fi n ṣere ifẹ, ibẹ naa ni ọna ti wọn n gba tọ̀.

Lati waa jẹ ki irinṣẹ pataki ti wọn fi n pe ọ l'ọkunrin yii maa mọ tonitoni nigba gbogbo, ko si le ṣiṣẹ rẹ bo ṣe tọ, eyi lohun tawọn akọṣẹmọṣẹ nipa rẹ sọ.

Àwọn ohun tí yóò mu ǹnkan ọmọkùnrin rẹ wa ni ìmọ́tótó

Maa fi omi to lọ wọọrọ fọ nnkan ọmọkunrin rẹ nigba to o ba n wẹ lojoojumọ.

Bi wọn ko ba ti i dákó fun ọ, rọra fa awọ to bo oju ‘kinni’ rẹ soke jẹjẹ to o ba fẹẹ wẹ, ko o si fọ isalẹ rẹ daadaa.

Bi o ko ba fọ abẹ awọ naa daadaa, kinni kan ti wọn n pe ni ‘Smegma’ yoo maa kora jọ sisalẹ abẹ rẹ.

Akojọpọ Smegma yii maa n run, o si le fun ọ loorun ti ko daa.

Ki nnkan ọkunrin maa baa gbẹ ni Smegma yii wa fun, ori nnkan ọkunrin ati isalẹ rẹ lo si maa n wa.

Bi Smegma ba fi kora jọ pọ sinu awọ nnkan ọkunrin, yoo bẹrẹ si i run, yoo si jẹ ko ṣoro lati fa nnkan ọkunrin ti wọn ko ti i da naa pada sinu.

Kokoro aifojuri ti wọn n pe ni Bacteria ni yoo pada da sara ọkunrin.

Eyi le jẹ ki ori nnkan ọkunrin bẹrẹ si i mu awọ pupa jade, eyi toyinbo n pe ni balanitis.

Ti o ba ni ọmọkunrin kekere lọwọ, awọn akọṣẹmọṣẹ nipa nnkan ọkunrin n gba ọ niyanju lati ma ṣe fipa fa awọ to bo kinni rẹ kuro, nitori o le fa inira ati ijamba fun un.

Idi ti wọn fi sọ bẹẹ ni pe o ṣẹe ṣe ki awọ yii ṣi lẹ pọ mọ nnkan ọmọkunrin naa, ko ma ṣe e ya tan lọtọọtọ.

Fun awọn ọmọde bi eyi, dandan kọ ni ka fọ inu abẹ awọ wọn.

Bi o ṣe le ṣe e ti egbo ko ni mu ọ lorii nnkan ọmọkunrin rẹ

Gẹgẹ bi awọn onimọ sẹ sọ, ti o ba n fi ọṣẹ ati awọn ipara pa nnkan ọmọkunrin rẹ ju, o le fa egbo tabi inira.

Bi o ba ti fọ nnkan ọkunrin rẹ lẹẹkan lojumọ pẹlu omi to lọ wọọrọ, ti o si fi aṣọ to mọ nu un, o ti to fun ilera pipe.

To ba wa jẹ́ pe dandan ni ki o lo ọṣẹ lati fọ ọ, lo eyi ti ko ni kẹmika tabi oorun. Eyi yoo adinku ba inira yoowu to le fẹẹ ti ara ọṣẹ.

Yatọ si eyi, ko dara lati lo atike tabi lọfinda oloorun si nnkan ọmọkunrin rẹ, nitori pe o le fa inira fun ọ.

Ìtọ́jú ẹpọ̀n àti agbègbè ojú ara

Ma ṣe gbagbe lati maa fọ isalẹ nnkan ọkunrin rẹ ati agbegbe ti ẹpọn wa.

Òógùn ara ati irun le kora jọ ko si maa run oorun to ti ko dara, gẹgẹ bo ṣe maa n ri bi abiya eeyan ko ba mọ.

Isalẹ ẹpọn yii nilo ki ọkunrin maa fọ ọ deede, ki oogun ara maa baa kora jọ sibẹ, paapaa bo ṣe jẹ pe ibi ikọkọ ta a ti wọ awọtẹlẹ si i fun ọpọlọpọ wakati lojumọ ni, ti atẹgun gidi ko si le debẹ .

Bakan naa ni ki o tun ri i daju pe isalẹ ẹpọn ati iho idi rẹ n mọ tonitoni, ki oorun buruku ma maa jade lati ibẹ.

Ma a wo isalẹ ẹpọn rẹ deede lati mọ daju pe ko wu, nnkan kan ti ko si nibẹ tẹlẹ ko si di sibẹ.

Alaafia fun gbogbo ọkunrin!