'Mo di akọ̀wé àgbà lẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn òbí kò fi mí sílẹ̀ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí mo ní'

Àkọlé fídíò,
'Mo di akọ̀wé àgbà lẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn òbí kò fi mí sílẹ̀ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí mo ní'
Kayode Wahab

Lára àwọn akọ̀wé àgbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara yàn ní ọdún 2023 ni Mallam Abdullahi Wahab Kayode.

Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ló máa ń là kàkà láti dé ipò yìí nítorí òpin tí èèyàn le ga dé lẹ́nu iṣẹ́ ọba ni.

Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn àkàndá èèyàn yóò dé ipò yìí ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Mallam Kayode nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun nígbà tí wọ́n kéde òun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn akọ̀wé àgbà náà.

Ó ní òun kò lérò pé òun le dé ipò náà nítorí ìpèníjà tí òun ní àti pé níṣe ni òun bú sẹ́kún lọ́jọ́ náà.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèníjà ni òun kojú nígbà tí òun ń dàgbà látàrí ìpèníjà ara tí òun ti ní láti ìgbà tí òun ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́rin.

Ó ní àwọn òbí òun sọ fún òun pé àìsàn ìgbóná ló dààmú òun tó sì wọ́ sí ẹsẹ̀ fún òun.

Ó sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun kìí fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ nígbà tí òun wà ní kékeré nítorí ìpèníjà ara tí òun ní àmọ́ àwọn òbí òun ni kò gbà fún òun.

Malaam Kayode ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni bàbá òun máa gbé òun kọ́rùn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ nítorí àti ra ọjọ́ ọ̀la tó dára fún.

“Bàbá àti ìyá mi lọ takú pé ṣebí ọpọlọ kọ́ lọ ń dùn ọ, gbogbo ọ̀nà tó ó bá gbà, o gbọ́dọ̀ kàwé, kòdá àárín ìgbà kan wá tó jẹ́ wí pé kọ́ńkọ́ńlọ́rùn ni bàbá mi yóò gbé mi.”

Ó fi kun pé bí òun ṣe lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, girama títí tí òun fi jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga.

Ó ní lẹ́yìn tí òun sin orílẹ̀ èdè bàbá òun tán lọ́dún 1991 ni òun rí iṣẹ́ sí iléeṣẹ́ ìjọba Kwara tí òun sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà náà títí tóun fi dé ipò adarí.

Ó wà rọ àwọn òbí àti alágbàtọ́ tí wọ́n ní àwọn ọmọ tó ní ìpèníjà kan tàbí òmíràn láti yé fojú ẹni tí kò lè wúlò lọ́jọ́ iwájú wò wọ́n nítorí ipa tí àwọn òbí òun kó lórí òun ló gbé òun dé ipò tí òun wà lónìí.