Kí ló tún fa rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ láàrin ìyá, bàbá àti ìyàwó Mohbad tí wọ́n fi ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?

Oríṣun àwòrán, BBC/PUNCH/IamMohbad
Awọn eeyan lori itakun ayelujara tunti bẹrẹ si ni ma gbọ ariwo lọtun losi lori idi ti gbajugbaja olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ko ti fi wọ kalẹ lọ sun.
Bẹẹ ba gba, oku Mohbad ni wọn wu jade lẹyin ti wọn ti kọkọ sin-in si ilu Ikorodu, nipinlẹ̀ Eko.
Ọpọ igbejọ ati iwadii lo jẹ yọ lori ọrọ yii, bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ti mu ọpọ awọn eeyan ti wọn gbagbọ pe wọn jẹ afurasi to lọwọ ninu iku Mohbad.
Ọlọkan-o-jọkan ija, itahun-sira-eni ati lilọ jẹjọ ni kootu lori iku Mohbad lo ti waye laarin awọn obi, iyawo ati ọrẹ rẹ oloogbe, bẹẹ naa ni wahala ọhun ṣi n tẹsiwaju.
Baba Mohbad loun ko ni i sin oku oloogbe naa bi wọn ko ba wadii iru iku to pa a, ki iyawo rẹ, Wumi naa si ṣetan lati ṣayẹwo ẹjẹ ti yoo sọ ẹni to bi Liam, to n pe lọmọ Mohbad fun.
Bẹẹ lo ni iya Mohbad to n sunkun kiri bayii ti figba kan gbe e silẹ fọdun mẹwaa, to ba tiẹ lọ.
Wumi naa n fẹsun kan baba ọkọ rẹ pe ko laanu loju, bẹẹ ni iya Mohbad ko yee sọ pe ọkọ oun ti sin Mohbad ko too ku rara.
Bẹẹ naa si ni Ibrahim Owodunni (Prime boy) ọrẹ Mohbad tawọn ọlọpaa tun mu laipẹ yii naa n ba iyawo Mohbad fa awọn ẹsun kan.
Irọ ni pe mọ salọ fun ọdun mẹwaa- Iya Mohbad

Oríṣun àwòrán, ThePunch
Laipẹ yii ni Iya Mohbad, Abosede Adeyemo, fi omije oju ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Punch pe, gbogbo ẹsun ti baba Mohbad fi n kan oun ko ri bẹẹ.
Iya Mohbad ni oun ko gbe ọmọ oun silẹ sa lọ fọdun mẹwaa bi baba rẹ sẹ n ba oun jẹ kiri.
‘’Mi o fi ọmọ mi silẹ fọdun mẹwaa, irọ ni wọn pa.
‘’Baba wọn lo fẹẹ pa mi, o fẹẹ gun mi pa ni, mi o dẹ lọ naa nigba to fẹẹ pa mi. Afigba ti wọn ranṣẹ pe baba mi pe ki wọn waa mu mi.
‘’ Gbogbo nnkan ti Jossy (Baba Mohbad) foju mi ri ni mo mu móra, nitori baba mi o fẹ ki n fẹ ẹ, mi o dẹ le lọọ fẹjọ ẹ sun.
‘’Igba ti Mohbad ku, ko sọ fun mi."
Bakan naa ni iya Mohbad ṣalaye pe awọn to pa ọmọ oun pọ, ṣugbọn baba rẹ̀ gba beeli gbogbo wọn,
O sọ bo ṣe jẹ pe Sam Larry ati Naira Marley maa n lu Mohbad gan-an.
O ni Baba Mohbad ati Wumi rẹ gan-an tẹlẹ, owo lo da aarin wọn ru
Bi Iyawo ọmọ mi ko ba ṣe ayẹwo DNA, n ko ni sin ọmọ mi- Baba Mohbad

Joseph Aloba, Baba oloogbe salaye pe ohun kan ṣoṣo to n da eto isinku Mohbad duro lati bi oṣu mẹfa ti wọn ti hu jade ni ayẹwo DNA ti iyawo oloogbe, Wumi ko ti i ṣe.
Eyi kii ṣe igba akọkọ ti Ọ̀gbẹ́ni Aloba, yoo jade sita pe ayaafi ki iyawo ọmọ rẹ to di oloogbe ṣe ayẹwo DNA, lati safihan boya Mohbad lo ni ọmọ to gbe dani.
“O gbọdọ ṣe ni, o ni lati ṣe e nitori nnkan pato to n da eto isinku Mohbad duro niyen.
“Bakan naa a tun nilo esi ayẹwo ohun to pa Mohbad nitori a ko le kan wu jade lai ri pe a ṣe ohun to tọ ati eyi to yẹ.
“A ni lati duro fun awọn esi ki a to lọ ṣe eto isinku.”
"Mo ti ṣetan fun ayẹwo DNA, ẹ mu iwe aṣẹ ile ẹjọ wa"

Oríṣun àwòrán, IamMohbad
Wumi Aloba, iyawo oloogbe Mohbad ti rọ baba ọkọ rẹ, Joseph Aloba lati tete mu iwe aṣẹ ile ẹjọ wa fun ayẹwo DNA to n beere fun.
Saaju ni Wumi ti sọ pe oun ti ṣetan fun ayẹwo naa sugbọn oke okun ati Naijiria ni oun yoo ti ṣe e.
Laipẹ yii naa ni Wumi bọ si ori ayelujara lati kesi awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn gba oun nitori idunkooko ti oun ati ọmọ rẹ n koju.
O fẹsun kan baba naa pe, o ni dandan ni pe ki oun bimọ fun Mohbad, to si jẹ ohun iyalẹnu pe o n beere fun ayẹwo DNA.
“N ko fẹ bimọ nigba naa sugbọn baba sọ fun emi ati Mohbad pe ẹmi mimọ sọ pe ki oun ni ọmọ-ọmọ ti yoo ra posi fun oun, ti yoo si tun sin oun.
Nigba ti mo loyun, inu baba ọkọ mi si dun pupọ lori iroyin naa.
“Ki lo wa de ti bu ẹnu atẹlu ọmọ ti ọmọ rẹ fi saye lọ.”
O wa jẹ ko di mimọ pe oun ti ṣetan fun ayẹwo DNA, to si rọ baba ọkọ rẹ pe ko mu iwe aṣẹ ileẹjọ wa.
“Ẹ lọ mu iwe aṣẹ ile ẹjọ wa nitori aṣiko ti ya ki oju ti awọn ọta mi.”
Ki lo ti waye saaju?
Ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 ni iroyin nipa iku Ilerioluwa Oladimeji Aloba, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si MohBad, gbode.
Lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye ni ọpọlọpọ rogbodiyan ti bẹ silẹ, to fi di pe ileeṣẹ ọlọpaa ni lati dasi ọrọ.
Ninu fọnran kan to jade lẹyin iku oloogbe, Joseph Aloba to jẹ baba rẹ̀ ṣalaye pe oun ro pe abẹrẹ ti wọn fun un lo ṣekupa a.
“Nnkan ti mo ni pe abẹrẹ ti wọn fun lo ṣekupa. N ko mọ awọn eeyan to gbe lọ si ile iwosan sugbọn gẹgẹ bi nnkan ti mo gbọ, o bẹrẹ si ni ma bi lẹyin to gba abẹrẹ, ti wọn si tun gbe lọ si ile iwosan."
Ko pẹ si igba naa ni Ileeṣẹ ọlọpaa mu gbajugbaja olorin takasufe, Naira Marley, Primeboy ati Sam Larry, ti wọn si wa ni ahamọ fun igba diẹ lori pe iwadii fihan pe wọn mọ nipa ohun to ṣekupa Mohbad.















