Mo ṣe ìlérí lati da ọmọ Mohbad pọ̀ mọ́ ọmọ tọ́ - Bella Shmurda

Aworan Bella Shmurda àti Mohbad

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajugbaja olorin takasufee nni, Bella Shmurda ti ṣe ileri lati maa gbọ gbogbo bukata ọmọ ti ọrẹ rẹ Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ mọ si Mohmad to di oloogbe fi silẹ laye.

Shmurda, ninu ọrọ to gbe sori opo ayelujara rẹ, ni oun si n tiraka lati gbagbe nípa iku Mohbad, ẹni to jade laye ninu oṣu kẹsan an ọdun 2023.

O ni oun to dun pupọ ni pe ọmọ oun ti oun sọ ni orukọ Mohbad ko ni dagba mọ ẹni to n jẹ orukọ naa.

"Lati igba to ti ku ni mo ti di ọmuti, ọmọ mi Abiola Imole ko ni mọ ẹni tí oun ba jẹ orukọ"

O wa ṣeleri pe oun yoo ri pe oun tọju ọmọ Mohbad, Laim gẹgẹ bii ọmọ oun.

"O sọ fun mi pe ki ye ke. Mo n igbiyanju. Mo lero pe daada lowa ni bi to wa nítorí o ti pẹ diẹ tí inu mi ko ti dun.

"Mo kan mu ọtí ati mo sì n gbinyanju lati tẹsiwaju.

"O dun pe Abiola Imole ko ni anfani lati mọ ẹ sugbọn fi ọkan rẹ balẹ, ma sọ itan rẹ ati pe ma tọju ọmọ rẹ naa.

"Ma jẹ ki ifẹ wa laarin awọn ọmọ wa."

Ti ẹ ko ba gbagbe, nínu oṣu kẹsan an ni Gbajugbaja olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad jade laye.

Iku rẹ fa ọpọlọpọ awuyewuye kakiri orilẹede Naijiria.

Ileeṣẹ Ọlọpaa kede laipẹ pe awọn ti mu awọn afurasi to ṣeeṣe ki wọn lọwọ ninu iku Mohbad ti igbẹjọ si ti bẹrẹ lori iku naa.