Ìwádìí BBC tú àṣírí bí àwọn olùkọ́ kàn ṣe n lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ làlùbami
Ki lo n ṣẹlẹ lawọn kilaasi ile ẹkọ lorileede Kenya?
Ibi ibeere yi la ti fẹ tibi lẹbẹ mu ọọlẹ jẹ lori iwadii ti ẹka iwadii BBC tun tan imọlẹ si lawujọ.
Lọtẹ yi eyi to nii ṣe pẹlu ilukulu tawọn olukọ n lu awọn akẹkọọ lorileede Kenya la tọ pinpin rẹ.
Ninu ohun taa mu bọ ni pe iwa ilukulu akẹkọọ yi ti gbogo ti awọn obi,alagbatọ ati awọn ọlọdani si ti n beere idajọ ododo ni paapa fawọn akẹkọ́ọ ti wọn ba gba ibi ilukulu yi dero ọrun.
Ilu Mombassa ni akọroyin wa kọri si to si ti n ṣe alabapade awọn obi ti awọn ọmọ wọn koju ilukulu lọwọ awọn olukọ wọn.
Iru ẹsẹ wo lawọn ọmọ yi ṣẹ ati pe ki ni ijọba n gbe ni igbesẹ lati koju iwa buruku to gbode lawujọ yii?
Olukọ lu ọmọ wa, diẹ lo ku ki ẹmi bọ lọrun rẹ
Lara awọn idile taa kan si ni idile ti akẹkọọ Caleb Mwangi ti wa.
Oju ọmọ ọdun mẹẹdogun yi ati awọn obi rẹ ri to koda diẹ lo ku ki ẹmi rẹ bọ lẹyin ti olukọ rẹ lu lalubami ni kilaasi.
Ki ni ohun ti olukọ sọ pe o jẹ ẹṣẹ rẹ?
Caleb sọ pe olukọ ati akẹkọọ ẹgbẹ rẹ kan lu oun nitori pe oun jẹ ounjẹ ju lasiko ti wọn n jẹ ounjẹ aarọ.
Baba Caleb ṣalaye pe nigba toun yoo fi ri ọmọ oun ni ile ẹkọ rẹ''ko le dide lori ibusun rẹ bẹẹ ko le sọrọ. Mo tara gbe lọ si ile iwosan. Ọjọ mọkanla lo lo ni ẹka ICU tori pe o dakẹ lọ gbọrangandan ni''
Ọgbẹ to wa lẹyin Caleb pọ debi pe wọn ni lati bu ẹran ara rẹ lati fi bo awọn ibi ti o ya nitori ilukulu ti wọn lu akẹkọọ naa.
Ọwọ awọn agbofinro pada tẹ olukọ yi ati akẹkọọ to ni pe ko lu ọmọ naa.
Awọn meji ti foju wina ofin.
Wọn fofin de lilu ọmọ lawọn ile ẹkọ Kenya ṣugbọn awọn olukọ kan keti ikun
Lọdun 2001 ni ijọba Kenya kede pe awọn fofin de ki awọn olukọ maa bo ẹgba fawọn akẹkọọ.
O ti le ni ogun ọdun ti ofin yi ti wa nilẹ ṣugbọn awọn diẹ bayi lo n tẹle aṣẹ yi.
O ṣeni laanu pe Caleb nikan kọ lo n fojuwina iru ijiya yi.
Lọpọ igba awọn akẹkọọ a maa faraya yanayana koda lilu tawọn olukọ n lu ọmọ mii a maa ja si iku fun wọn.
Laarin ọdun mẹta sẹyin si isinyi, ilọpo awọn ọmọ to n gba ibi lilu yi dero ọrun ti lekun si nilọpo mẹrin lati mẹsan di mọkandinlọgbọn lọdun yi.



