Wo òfin tuntun tí ìjọba Canada gbé kalẹ̀ fún àwọn tó bá fẹ́ẹ́ ‘Jápa’ láti oṣù kejìlá ọdún yìí

Oríṣun àwòrán, Ami idanimọ Canada/Ghetti
Minisita fun ileeṣẹ aṣọbode orileede Canada, Marc Miller ti sọ pe awọn yoo bẹrẹ eto miran lati maa fi ṣayẹwo finifini nipa awọn to ba fẹẹ wa kawe ni fasiti wọn, ko to di pe wọn fun wọn ni iwe igbaniwọle.
O ni eyi yoo jẹ ki wọn le mọ awọn to jẹ ayederu ninu awọn to n wọle sibẹ lati kawe, ati awọn to jẹ ojulowo akẹkọọ lorileede wọn.
Marc Miller lo sọrọ naa lọjọ Ẹti, Fraide to kọja wi pe ọpọ awọn eeyan lo n fi kikawe nilẹ Canada lu jibiti, to si lawọn ti ṣetan lati di iwa naa ku bayii.
Ni ibẹrẹ oṣu yii, ọrọ jibiti iwe igbaniwọle sile-ẹkọ ti a mọ si ‘Admission Letter’ pọ rẹpẹtẹ lati ọdọ awọn akẹkọọ to wa lati orileede miran, nigba ti wọn ṣakiyesi pe ayederu iwe ni wọn lo lati fi wọle si Canada.
Loju ẹsẹ ni wọn ti bẹrẹ sii gbe iwe pada sile rẹ le gbogbo wọn lọwọ lai fi asiko ṣofo.
Canada jẹ orileede kan to gbajumọ daadaa fun awọn akẹkọọ lati orileede miran pẹlu bi iwe ẹri iṣẹ ṣe rọrun lati tete gba nibẹ.
Ki ni yoo wa ṣẹlẹ si awọn akẹkọọ to n wa lati orileede miran bayii?
Ṣa o, lati oṣu Disẹmba lọ, Miller sọ pe awọn ile-ẹkọ yoo nilo lati fidi iwe ẹri igbaniwọle sile-ẹkọ mulẹ daadaa pẹlu ileeṣẹ aṣọbode.
Ijọba Canada tun ti bẹrẹ sii gbe akọsilẹ ti wọn pe ni “recognized institutions list” fun ọdun 2024 jade, eyi ti yoo fun awọn akẹkọọ to n bọ lati orileede miran ni anfaani lati mọ awọn ile-ẹkọ ti wọn yoo ti ri iranlọwọ ohun ti wọn n fẹ.
Awọn ile-ẹkọ naa ni wọn yoo iwe ẹri akẹkọọ lati tẹsiwaju iforukọsilẹ wọn.
Miller sọ fun awọn akọroyin pe “ohun ti a n ri ni okoowo alasiko perete to ni ere lai wo ti iya ọjọ iwaju, ti a si ni lati yii pada bayii.”
Canada gbe oju le awọn to n wọle lati orileede miran lati le mu orileede wọn tẹsiwaju nipa eto ọrọ aje ati iye awọn to wa nibẹ ti wọn tri n dagba lọ.
Alakoso agba orileede naa, Justin Trudeau tun ti n nifẹẹ si bi awọn eeyan ṣe n wọle silẹ wọn lọdọọdun.
O ni ọdọọdun ni eto ẹkọ wọn n pa owo to to biliọnu mejilelogun dọla ti Canada (C$22b), eyi to jẹ biliọnu $15.9b, to si tun n pese iṣẹ ti ko din ni ẹgbẹrun lọna.
Akọsilẹ ọdun 2022 fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹrun lọna ọgọrin akẹkọọ ni wọn gba wọle lati orileede miran, to si jẹ pe ẹgbẹrun lọna awọn ẹẹdẹgbẹrun fun ọdun 2023.
Iroyin to wa lati Bloomberg jẹ ko di mimọ pe ori eto ẹkọ nikan ni orileede Canada gbojule julọ fun ilọsiwaju eto ọrọ aje wọn
A gbọ pe ida marun owo ti awọn akẹkọọ to n wa lati orileede miran n san ni awọn to jẹ ojulowo ọmọ ilẹ Canada n san lowo ẹkọ, eyi to jẹ ki wọn maa da oriṣiriṣi ile-ẹkọ silẹ fawọn eeyan.
Ni ẹkun to tobi julọ lorileede Canada, iyẹn Ontario, wọn sọ pe wọn ti yọ owo ti awọn akẹkọ ọmọ bibi Canada n san kuro.
Fun idi eyi, lọdun 2021, awọn akẹkọọ to n wa lati okeere n san ida mejidinlaadọrin owo ile-ẹkọ l’awọn ile-ẹkọ to wa ni Ontario.
Ṣugbọn fun awọn akẹkọọ lati orileede miran, anfaani ni igbaniwọle si kọlẹẹji jẹ fun wọn lati fi gba iwe igbelu.
Miller, ninu ipade oniroyin to ṣe sọ pe ijọba fẹẹ fi gbedeke si iye fi ti wọn yoo maa fun awọn akẹkọọ agbaye to n wa sibẹ lati kawe.
Ko si nnkan meji to si fa, bi ko ṣe ti ọrọ to n lọ nigboro nipa bi ero ṣe n wọ orileede naa lati kawe, to si n mu iṣoro ba ile gbigbe.















