Lionel Messi gba àmì ẹ̀yẹ Ballon d'Or fún ìgbà kẹ́jọ

Ballon d'Or: Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, getty images

Agbabọọlu orilẹ-ede Argentina ati Inter Miami, Lionel Messi ti gba ami ẹyẹ Ballon d’Or awọn ọkunrin fun igba kẹjọ.

Ẹni ọdun mẹrindinlogoji naa ni wọn fun ni ami ẹyẹ yii nibi ayẹyẹ to waye niluu Paris, lorilẹ-ede France lẹyin to ran orilẹ-ede rẹ lọwọ lati gba ife ẹyẹ agbaye FIFA lorilẹ-ede Qatar lọdun to kọja.

Agbabọọlu orilẹ-ede England ati Real Madrid, Jude Bellingham lo gba ami ẹyẹ ‘Kopa Trophy’ fun agbabọọlu to dangajia julọ lagbaye ti ọjọ ori rẹ ko tii to ọdun mọkanlelogun.

Messi fidi agbabọọlu Machester City, Erling Haaland janlẹ, lati gba ami ẹyẹ Ballon d’Or ọdun yii.

Nigba ti Kylian Mbappe, to n gba bọolu fun orilẹ-ede France wa ni ipo kẹta.

Nigba to n sọrọ lẹyin ami ẹyẹ naa, Messi ni “Inu mi dun lati pada wa si ibi lati gbadun akoko yii, inu mi tun dun lati mu ala mi ṣẹ nipa gbigba ami ẹyẹ ife ẹyẹ agbaye.”

“Mi o gbagbọ pe mo le ṣe irufẹ aṣeyọri yii ninu iṣe ti mo yan laayo.”

“Mo jẹ oloriire lati wa lara awọn ọmọ ikọ to dara julọ ninu itan.”

Akọroyin ọgọrun un kaakiri agbaye lo maa n dibo yan ẹni ti yoo gba ami ẹyẹ Ballon d'Or.

Ta ni yóò gba àmì ẹ̀yẹ Ballon d’Or lálẹ́ òní?

Aworan Messi, Haaland ati Mbappe

Oríṣun àwòrán, GETTY

Loni, ọjọ Aje, ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ni eto ami ẹyẹ agbabọọlu to fakọyọ julọ lọkunrin ati lobinrin yoo waye lorileede France.

Aago mẹfa irọlẹ oni tii ṣe aago ti wọn n lo ni Naijiria ni eto ọhun yoo bẹrẹ, ti gbogbo agbaye yoo si lanfaani lati bawọn foju lounjẹ bi eto naa ṣe n lọ.

Gbọngan ''Theatre du Chatelet'' to wa nilu Paris, orileede France ni eto naa yoo ti waye ti wọn yoo si ṣafihan rẹ lori ikanni ayelujara wọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Karim Benzema to n gba iwaju fun ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid tẹlẹ lo gba aami ẹyẹ Ballon d’Or t’ọdun to kọja.

Sadio Mane ati Kevin de Bruyne ni wọn figagbaga pẹlu Benzema ko to ja mọ ọ lọwọ.

Lọdun yii, awọn gbajugbaja agbabọọlu mẹta nii, Lionel Messi to n gba fun Inter Miami; Erling Haaland to n gba bọọlu fun Manhester City ati Kylian Mbappe to n gba bọọlu fun Paris Saint-Germain ni wọn jọ n figagbaga.

Messi lo gba ifẹ ẹyẹ bọọlu agbaye lọdun to kọja pẹlu Argentina, to si tun gba agbabọọlu to dara julọ ninu idije ọhun.

Bẹẹ lo tun gba ife ẹyẹ ilẹ Faranse, iyẹn French League One pẹlu PSG ko to lọ darapọ ẹgbẹ agbabọọlu Inter Miami ni saa yii.

Haaland, gba ife ẹyẹ Champions League, FA Cup ati Premier League pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City.

Bẹẹ lo tun gba goolu mejilelaadọta sinu awọn ninu idije saa to lọ eyi to mu fakọyọ gẹgẹ bi agbabọọlu to pegede ni Premiership.

Mbappe, ni tiẹ gbe ikọ ẹgbẹ agbabọọlu France de aṣekagba idije bọọlu agbaye naa nibi ti wọn ti fidirẹmi lọwọ Argentina ati Messi.

O gba bata oni goolu gẹgẹ bi agbabọọlu to gba goolu sáwọ̀n julọ lọdun to kọja, to si tun gba French League 1 pẹlu PSG.

Lara awọn agbabọọlu miran to tun wa ninu ifigagbaga ọhun ni Victor Osimhen, André Onana, Josko Gvardiol, Karim Benzema, Jamal Musiala, Mohamed Salah, Jude Bellingham, Bukayo Saka, Randal Kolo Muani, Kevin De Bruyne, Bernardo Silva, Emiliano Martínez ati Khvicha Kvaratskhelia.

Awọn yooku ni Rúben Dias, Nicolo Barella, Yassine Bounou, Martin Ødegaard, Julián Álvarez, Ilkay Gündogan, Vinícius Júnior, Rodri, Lautaro Martínez, Antoine Griezmann, Robert Lewandowski, Kylian Mbappé, Kim Min-jae, Luka Modric ati Harry Kane.

Ibeere ti awọn eeyan n beere bayii ni pe ta ni yoo gba ifẹ ẹyẹ bọọlu ilẹ Faranse ti a mọ si Ballon d’Or ti ọdun 2023?