Kí ni òru Laylatul-Qadri àti pé ìgbà wo ló yẹ kí èèyàn wa sí nínú oṣù Ramadan?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Òru Laylatul-Qadri tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí òru abiyì ní èdè Yorùbá jẹ́ òru tí gbogbo mùsùlùmí káàkiri àgbáyé gbàgbọ́ pé kò sí òru tó dára to gẹ̀gẹ̀ bí ó ṣe wà nínú ìwé mímọ́ Kùránì.
Onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam kan ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Sheikh Ahmad Atiku Auwwalní kò sí òru kankan tó dára tó òru abiyì yìí káàkiri àgbáyé.
Sheikh Awwal ní Allah jùwe bí òru yìí ṣe lágbára tó nínú Súrà al-Qadri nínú ìwé mímọ́ Kùránì.
Ó ní Súrà náà ṣàlàyé bí òru Laylatu-Qadri ṣe dára ju ẹgbẹ̀rún òru lọ tó sì ní ìjọsìn tí èèyàn bá ṣe ní òru ọjọ́ yìí máa ń ní oore ju òru àwọn ọjọ́ yòókù lọ.
Ó ṣàlàyé pé òru Laylatul-Qadri gan-an ní Ọlọ́run sọ ìwé mímọ́ Al-Kúràní kalẹ̀ fún Ànábì.
Ní òru ọjọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àlàyé rẹ̀ ni ọjọ́ tí Ọlọ́run máa ń ṣe ìpinnu lórí àwọn nǹkan tí yóò bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá láàárín ọdún yálà ní rere tàbí ìdàkejì.
Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òru yìí kìí ṣe òru tó yẹ kí mùsùlùmí fi ṣeré rárá àti pé ó yẹ kí wọ́n máa lò ó láti fi tọrọ àwọn nǹkan rere tí wọ́n bá ń fẹ́ ni.
Ọjọ́ wo gan ní òru Laylatul-Qadri máa ń jẹ́?
Onímọ̀ ẹ̀sìn Islam náà ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí Ànábì Muhammad ṣe là á kalẹ̀, nínú ọjọ́ mẹ́wàá tó gbẹ̀yìn nínú oṣù Ramadan ni òru yìí máa ń wà.
Ó ní láti òru ọjọ́ Kọkànlélógún sí ìparí oṣù náà ni èèyàn le wá òru náà sí.
“Ànábí sọ fún àwọn mùsùlùmí láti wá òru Laylatul-Qadri sí òru ọjọ́ 21, 23, 35, 27 àti òru 29.”
Ó ní ohun tó tọ́ fún mùsùlùmí tó bá fẹ́ jẹ àǹfàní òru yìí ni láti má sùn ní àwọn òru ọjọ́ tí Ànábì là kalẹ̀ yìí, nítorí wọn kò mọ ọjọ́ tó máa jẹ́ nínú wọn.
Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n fi àyè sílẹ̀ láti ṣe àdúrà gidigidi sí ọba tó dá wọn láwọn ọjọ́ yìí.
Ó fi kun pé ó ṣeéṣe kí Laylatul-Qadri wáyé ní ọjọ́ ọ̀tọ̀ sí ti ọdún tẹ́lẹ̀, èyí tó túmọ̀ sí pé tí òru Laylatul-Qadri bá wáyé ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Ramadan ọdún yìí, ó ṣeéṣe kó yípadà ní ọdún tó bá tẹ̀le.
“Àmọ́ àwọn ìtàn kan sọ pé ọjọ́ Kẹtàdínlógún ló sábà máa ń jẹ́ àti pé àwọn sàábé Ànábí kan búra pé ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù ni Laylatul-Qadri máa ń jẹ́,” Sheikh Awwal sọ.
Ó ní Ànábí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹni tó bá gba Ọlọ́run gbọ́, tó sì tún gba òru yìí gbọ́, tó dìde kírun, ṣàdúrà ní òru ọjọ́ yìí ni Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà rẹ̀, tí wọn yóò sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti ṣẹ̀ sẹ́yìn rẹ́ fun.
Kí ni àwọn nǹkan tó yẹ kí ènìyàn ṣe ní òru yìí?
Sheikh Awwal ní onírúurú ohun ìjọ́sìn ni èèyàn lè ṣe ní òru yìí bíi kíka ìwé mímọ́ Kùránì àti títọrọ àforíjì lọ́wọ́ Ọlọ́run tàbí kí èèyàn máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́run.
Àmọ́ ó ní àdúrà ni Ànábì máa ń ṣe jù, nígbà ayé rẹ̀, ní òru yìí. Èèyàn tún lè fi kíka Kùránì tàbí ṣíṣe àsíkìrí kún àdúrà rẹ̀.
Ó tẹ̀síwájú pé yíyan nọ́fílà ní àárín òru àwọn ọjọ́ mẹ́wàá tó gbẹ̀yìn oṣù Ramadan ṣe pàtàkì púpọ̀ nítorí àwọn ọjọ́ yìí ni àwọn oore pọ̀ sí jùlọ.
Ó ní èyí ni Ànábì àti ìdílé rẹ̀ ṣe máa ń lékún nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run ní ọjọ́ mẹ́wàá tó gbẹ́yìn oṣù Ramadan.
Ó sọ pé èyí túmọ̀ sí mùsùlùmí kò gbọdọ̀ ní ìfàsẹ́yìn nínú bó ṣe ń jọ́sìn fún Ọlọ́run ní ọjọ́ mẹ́wàá tó gbẹ́yìn oṣù Ramadan yìí.
Mallam Awwal ní kò sí iye nọ́fílà tí èèyàn kò lè yàn ní òru yìí, kò sí iye kan pàtó tó pọn dandan àmọ́ kí wọ́n ri dájú pé wọ́n yan nọ́fílà.
Bákan náà ló ní èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí ní yan nọ́fílà yìí lẹ́yìn tó bá kírun Ishai tán ní alẹ́ kó tó di pé ó sùn.
Ó ní èèyàn lè ka ìrun Áṣámú gẹ́gẹ́ bí ìrun nọ́fílà àmọ́ tó ń wáyé ṣájú kí èèyàn tó sùn àti pé náfílà ti tòru tí wọ́n ń pè ní Tahajud jẹ́ èyí tí èèyàn máa dìde lóru láti yàn.
Níbo lo dára láti yan nọ́fílà ní òru Laylatul-Qadri?
Mallam Awwal ní ó dára láti yan nọ́fílà òru Laylatul-Qadri ní mọ́ṣáláṣí pàápàá jùlọ fún àwọn ọkùnrin nítorí Sunnah Ànábì ni ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́.
Ó ní ẹ̀rí wà pé Ànábì àtàwọn sàábé rẹ̀ máa ń lọ yan nọ́fílà náà ní mọ́ṣáláṣí ni.
Ó fi kun pé kìí ṣe dandan fún àwọn èèyàn láti máa lọ sí mọ́ṣáláṣí láti yan nọ́fílà yìí, tó bá jẹ́ pé kíki nílé ló bá rọ̀ wọ́n lọ́rùn kò ohun tó burú níbẹ̀.
Fún àwọn obìnrin, ó ní ilé ló ti dára jù kí obìnrin ti máa yan nọ́fílà tàbí kírun tirẹ̀ ju mọ́ṣáláṣí lọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ tí Ànábì fi lélẹ̀.
Ṣùgbọ́n ó ní tí àwọn obìnrin náà bá fẹ́ lọ sí mọ́ṣáláṣí kò sí ohun tó burú níbẹ̀ àmọ́ ohun tó dára jù ni pé kí wọ́n máa ṣe àdúrà wọn nílé.















