Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Eyi ni akojọpọ awọn ohun to n ṣẹlẹ to tayọ kaakiri agbaye. Lọsẹ yii, arun onigbameji, Kọlẹra ti bẹ silẹ ni Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii
Ijọba ni arun naa ti tan de ipinlẹ ọgbọn ninu mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, koda, o ti mu ọpọ ẹmi lọ.
Oniruru apẹrẹ ni arun naa maa n fi lede, o si ni awọn ohun ti o le ṣe lati dena, ati lati tọju rẹ.
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti buwọlu iyansipo Oba Akinloye Owolabi Olakuleyin gẹgẹ Olubadan ti ilẹ Ibadan.
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti gomina fi lede.
Makinde ni oun paṣẹ naa pẹlu ilana ti iwe ofin ipinlẹ naa gbe kalẹ lọdun 2000 nipa ọba jijẹ.
Olakunleyin ni yoo jẹ Olubadan ẹkẹtalelogoji niluu Ibadan.