Ìbanilórúkọjẹ́: Davido fún Dammy Krane ní wákàtí mẹ́rìnlélógún láti pa ohun tó kọ sórí ayélujára rẹ́ tàbí kó fojú ba ilé ẹjọ́

Aworan davido ati Dammy Krane

Oríṣun àwòrán, Davido @ Facebook/Dammy Krane Instagram

David Adeleke, olorin taka sufee tawọn eeyan mọ si Davido, ti kọ iwe ofin si akẹgbẹ rẹ, Oyindamọla Emmanuel (Dammy Krane), pe ki o pa ohun to kọ nipa oun lori ayelujara rẹ laarin wakati mẹrinlelogun.

Lọọya agba ni Naijiria, Chikaosolu Ojukwu, (SAN) ni Davido gbeṣẹ naa fun, oun si kọwe ifisun si Dammy Krane pẹlu alaye pe o ba onibaara oun, Davido lorukọ jẹ.

Wakati mẹrinlelogun ti i ṣe ọjọ kan ni Davido fun Dammy lati pa ohun to kọ soju opo X rẹ nipa oun rẹ, ati tawọn oju opo mi-in to ti kọ.

Wọn ni bi ko ba ṣe bẹẹ, ija ofin lawọn yoo ba a ja.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹfa ọdun 2024 yii ni Dammy Krane kọ ọrọ naa soju opo X rẹ .

Kí ni Dammy Krane kọ nípa Davido?

Ọrọ kan ni Dammy Krane kọ soju opo rẹ pe,

‘’ Ma ṣe ṣegbeyawo nitori obinrin rẹ ká ọ pẹlu obinrin miran. Wọn gbe-ìyà-wò. Ẹ ku oriire owe bowe.’’

Wọn ni Davido to fẹẹ ṣegbeyawo laipẹ yii pẹlu ololufẹ rẹ, Chioma Roland, lo n fi ọrọ naa ba wi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ati pe nitori Chioma ka Davido mọ ibi aṣemaṣe pẹlu obinrin mi-in ni Davido ṣe fẹẹ fi igbeyawo tu Chioma ninu.

Bakan naa ni wọn ni Dammy tun sọ pe Davido ko le fi ifọkanbalẹ na owo to ni.

Eyi lo mu Davido ati lọọya rẹ kọ lẹta si Dammy Krane lati pa ohun to kọ naa rẹ laarin wakati mẹrinlelogun.

Wọn fi kun un pe o si tun gbọdọ dẹkun ikọkukọ ti i ki i ṣe otitọ nipa Davido to gbajumọ kaakiri agbaye.

Apa kan lẹta naa ka bayii pe,

‘’ Gbajumọ kaakiri aye ni onibaara wa, olorin to ti gba ami-ẹyẹ kaakiri to si tun n fowo ṣaanu kiri ni.

Koda, onibaara wa ti gba ami ẹyẹ ‘Order of the Niger’ (OON) to jẹ ti ijọba apapọ.

Ó waa sọ fun wa pe niṣe niwọ n kọ awọn ọrọ ibanilorukọjẹ ti ki i ṣe otitọ nipa oun.

Iru iwa yii ko lorukọ meji ju idunkooko mọ ni lori ayelujara lọ.

Ninu awọn ohun ti o kọ nipa onibaara wa naa lo ti pe ni oponu, o ni ko le pe ọ lẹjọ nitori otitọ ti iwọ n sọ’’

Eyi ati awọn nnkan mi-in ni agbẹjọro Davido ka gẹgẹ bi ẹsun si Krane lẹsẹ.

Wo lẹta naa nibi:

Lẹta ti lọọya Davido kọ si Dammy Krane

Oríṣun àwòrán, Ojukwu Chikaosolu & Co

Lẹta ti lọọya Davido kọ si Dammy Krane

Oríṣun àwòrán, Ojukwu Chikaosolu & Co