Ṣé lóòtọ́ọ́ láwọn ọlọ́kadà ṣekúpa ọlọ́pàá l’Eko tí wọ́n ṣì tún gorí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kadà? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Screenshot/@amahshedy2022/X
Fidio kan to n ṣafihan oku ọkunrin kan to wa loju popo tawọn ọlọkada ṣi n gori rẹ lọ bọ niluu Eko ti lu ori ayelujara pa papaa julọ itakun ayelujara X.
Ọpọ eeyan ti wọn fi fidio naa lede loju opo wọn ni wọn kọ akọle sori rẹ pẹ awọn ọlọkada lo pa ọlọpaa kan to n maa n dari lilọ bibọ ọkọ loju popo.
Ọpọ awọn eeyan yii lo sọ pe lọsan gangan ni wọn ṣekupa ọlọpaa to n dari ọkọ yii ti wọn ṣi tun n gori lẹ lọ bọ pẹlu ọkada wọn.
Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Bigwig Austin lori itakun ayelujara X ni tiẹ kepe ijọba ipinlẹ Eko loju opo X rẹ pe fidio ọkunrin kan tawọn eeyan kan ṣekupa lọsan gangan ti wọn ṣi tun n gori rẹ pẹlu ọkada wọn ti lu ori ayelujara pa.
O rọ ijọba ipinlẹ Eko lati wa nnkan ṣe lori iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
@Onye_Game sọ ni tiẹ pe awọn ọlọkada ti wọn wa lati Oke Oya si ipinlẹ Eko lati ṣiṣẹ ti ọpọ mọ si Aboki lo ṣeku pa agbero kan to jẹ ọmọ Yoruba lagbegbe Mile 2 niluu Eko.
Oun naa fi fidio bawọn ọlọkada ṣe n gori oku ọkunrin naa lọ bọ soju opo X rẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọlọpaa ipinlẹ Eko sọrọ lori iṣẹlẹ naa
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti sọrọ lori fidio oku ọkunrin naa tawọn ọlọkada n gori rẹ lọ bọ to lu ori ayelujara pa.
Ninu ọrọ rẹ to fi lede loju opo X rẹ, SP Hundeyin ṣalaye pe awọn ọlọpaa meji lo jade fun ra wọn lọna aitọ ti wọn ṣi tun wa awọn eeyan kan ti kii ṣe ọlọpaa kun ra ni Ọjọru ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹfa yii.
Hundeyin ṣalaye pe nibi ti wọn lọ lawọn ọlọkada kan ti ṣe ikọlu si wọn nibi ti ẹnikan to kọwọọ rin pẹlu awọn ọlọpaa naa ti ṣe kongẹ iku.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ si ni bawọn ọlọpaa meji naa ti wọn ti wa ni ahamọ wi bayii.
Bakan naa ni Hundeyin tun fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n wa awọn eeyan ti wọn kọwọọ rin pẹlu awọn ọlọpaa meji yii.
SP Hundeyin ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati fọwọ ofin mu awọn to ṣekupa ọkunrin naa.
O ni gbogbo awọn to wa nidi ọrọ naa ni yoo foju ba ile ẹjọ ti ọwọ ba ti tẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Screenshot















