Ó di Gbàǹjo o! Ìjọba Nàìjíríà fẹ́ ta ọkọ̀ òfúrufú Ààrẹ Tinubu àti méjì míràn láti fi ra tuntun

Oríṣun àwòrán, Others
Iléeṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà ti ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi fẹ́ ta mẹ́ta nínú àwọn ọkọ̀ òfurufú ààrẹ lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú awuyewuye ti wáyé lórí rẹ̀.
Ìjọba ní kò sí ìdí kankan tí àwọn fi fẹ́ ta àwọn ọkọ̀ òfurufú náà lọ ju pé àwọn ọkọ̀ òfurufú náà nílò àtúnṣe tí yóò sì ná àwọn ní owó gọbọi láti fi tún wọn ṣe.
Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lórí ètò ìròyìn, Abdul’Azeez Abdul’Azeez sọ fún BBC pé ọkọ̀ òfurufú mẹ́fà ni Tinubu bá ní iléeṣẹ́ ààrẹ nígbà tó gba ọ̀pá àṣẹ láti tukọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Abdul’Azeez ṣàlàyé pé èyí tó tóbi nínú àwọn ọkọ̀ òfurufú náà ni ààrẹ máa ń lò àmọ́ ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọkọ̀ òfurufú náà ló ń yọnu tó sì nílò àtúnṣe.
Ó fi kun pé láti ọdún pipẹ́ ni wọ́n ti ń lo àwọn ọkọ̀ náà, tí wọ́n sì ti ń yọnu tó nílò kí wọ́n ná owó ribiribi fún àtúnṣe wọn.
Ó ní èyí ló mú ààrẹ gbà pé ó sàn kí wọ́n tà wọ́n ju kí wọ́n ná owó gọbọi láti tún wọn ṣe lọ.
Abdul’Azeez tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé mẹ́ta nínú àwọn ọkọ̀ òfurufú náà, tó fi mọ́ èyí tí ààrẹ máa ń lò ni wọ́n máa tà.
“Tí wọ́n bá ta mẹ́ta nínú àwọn ọkọ̀ òfurufú náà, wọ́n máa wá ra ẹyọ̀kan péré tó dára, tí kò ní máa yọnu fi rọ́pò wọn,” ó ṣàlàyé.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ alábẹṣékélé lórí ètò ààbò nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin rọ ààrẹ láti ra ọkọ̀ òfurufú méjì - ọ̀kan fún ààrẹ, èkejì fún igbákejì ààrẹ.















