Sani Dangote's death: Aliko Dangote ṣàlàyé àwọn ǹkan tó ṣẹlẹ̀ kí abúrò rẹ̀ tó kú

Oríṣun àwòrán, Sani Dangote
Ààrẹ ilé iṣẹ́ Dangote Group, Alhaji Aliko Dangote ṣàlàyé inira ti ó ri bi o ṣe ń wo àbúrò rẹ̀ Sani Dangote ti o kú, ó ṣe àpàèjúwe ìrírí rẹ bi èyí tó burú jáì.
Dangote ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún gómìna ìpińlẹ̀ Eko nígbà kan rí Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lásìkò tó lọ kí wọn ku ara fẹraku ní ìlú Kano.
Sani, tó jẹ́ igbákejì oludari agba Dangote Group kú sí ilé ìwòsàn kan nílẹ̀ Amẹrika lọ́jọ́ Aiku ọ̀sẹ̀ yìí ti wọ́n si sin-ín l'Ọjọ́bọ ni ibojì to wà ní agboolé Alhassan Dantata ni Koki Sarari ni ìgbòrò Kano.
- Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha
- Àwọn alamí ìjọba kan ti wà láàrín àwa ajìjàgbara Yoruba Nation tó ń bínú pé Sunday Igboho ti ga ju àwọn lọ - Akintoye
- Alaafin Oyo fi ọkọ̀ bọ̀gìnnì dá ọmọbìnrin rẹ̀ tó gbé "First Class" jáde ní fásítì lọ́lá
- Pásítọ̀ onísọjí tó fí ipá bá olóyún oṣù mẹ́jọ sùn ní Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé
- Wọ́n ti ń bèrè lọ́wọ́ abúrò ọkọ mi pé èlò ni wọ́n fẹ́ gbà, ẹ ṣàánú wa o! - Ìyàwó Timothy tó kú sí Hilton Hotel Osun figbe ta
Lásìkò ìsìnkú náà ni ìwé ìròyìn NAN sọ pé Dangote ni "àsìkò tó nira fún ẹbí àwọn gidi ni, ó jẹ́ àsìkò ìdánwò, pàápàá jùlọ fún èmi. Tí ènìyàn bá ni irú àbúrò báyìí, tí ènìyàn bá pàdánù irú rẹ̀ yóò du ni gidi. Ó kú níwájú èmi, màámi àti àwọn ọmọ rẹ̀".
" Èyí tí ó duni jùlọ ni kí wọ́n sọ fún ènìyàn pé, àbúro rẹ ni wákàtí kan sii láti lò kí o tó kú, kí ènì náà sì ni láti dúro títí ti ẹ̀rọ àṣerànwọ ẹmi fi dákẹ́. Ó jẹ́ àsìkò tó buru gidi".
Ó ní "o ti pẹ́ ti a ti mọ̀ pé tí ẹ̀mí bá wà, dandan ni ikú. Àwa Mùsùlùmí a o mọ ẹ̀ni ti o kàn, o lè jẹ́ ọ̀la kódà ó le jẹ́ òní.
Dangote tó jẹ́ olówó jùlọ ni ilẹ Afirika, dúpẹ́ lọ́wọ́ Tinubu fún àbẹwò rẹ̀ ti pé yóò mu àdínkù bá ìnira ti ó n bá ẹbi àwọn fínra lọ́wọ́.
Tinubu nínú ìwé ìkẹ́dùn rẹ̀ , owó kò le ra ẹ̀mi ti kò sì sí nǹkan ti ẹnikẹ́ni le ṣe sii. Ó rọ àwọn ẹbi láti fi ọkàn wọn si ọdọ Ọlọrun kí wọ́n sì gbàdúra fún ẹmi ẹni to ti kú.


















