Davido ti kéde bí yóò ṣe ná ₦200m tó rí gbà fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, davido
Olorin takasufe, David Adeleke, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Davido ti kede pe oun yoo pin gbogbo owo to ri gba fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ si ile awọn ọmọ alainiya kaakiri Naijiria.
Iye owo ti Davido ni oun yoo pin sawọn ile awọn ọmọ alainiya naa jẹ òjìlénígba lé mẹwaa miliọnu naira lapapọ.
Davido lo kede igbesẹ naa ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Instagram rẹ lọjọ Abamẹta.
- Wọ́n ti ń bèrè lọ́wọ́ abúrò ọkọ mi pé èlò ni wọ́n fẹ́ gbà, ẹ ṣàánú wa o! - Ìyàwó Timothy tó kú sí Hilton Hotel Osun figbe ta
- Irú ikú wo gan ló pa àbúrò Dangote? Aliko Dangote ṣàlàyé àwọn ǹkan tó ṣẹlẹ̀ kí abúrò rẹ̀ tó kú
- Ó yẹ́ kí àwọn olóṣèlú kẹ́kọ̀ọ́ lára Goodluck Jonathan, olùfẹ́ ìrẹ́pọ̀ ni - Lawan
- Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha
- EndSARS Panel report: Amẹrika ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ìwàdìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn Lekki toll gate
- Buhari ní òun á gbé ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu yẹ̀wò
- Buhari buwọ́lu N656 bílíọ́nù owó ìdólà fún àwọn ìpínlẹ̀
- Nàìjíríà gba orúkọ burúkú lórí ìgbẹ́ yiyá síta gbángba
- Lẹ́yìn Titi Masha, Kwam 1 gbé ìyàwó tuntun, Emmanuella Ropo l'Abeokuta, bó ṣe lọ rèé
- Ìkúnlẹ̀ abiyamọ ò! Wo bí arábìnrin yìí ṣé bínú dá omi gbígbóná s'ará ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀
Atẹjade naa ni "Mo fẹ fi ẹmi imoore mi han si gbogbo awọn ọrẹ mi atawọn ololufẹ mi fun oun ti wọn ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii."
"Bii ere, bi awada ni mo fi bere lọwọ awọn ololufẹ mi pe ki wọn da owo jọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi mi ti yoo waye laipẹ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun mi pe awọn eeyan fun mi ni igba miliọnu naira."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Lẹyin naa lo sọ pe oun yoo fi aadọta miliọnu naira kun igba miliọnu naira ti wọn da fun oun lati pin si awọn ile awọn ọmọ alainiya kaakiri Naijiria.
O ni "Inu mi maa n dun lati ṣoore fun awọn eeyan, idi ree ti inu mi ṣe dun lati kede pe gbogbo igba miliọnu naira ti mo ri gba ati aadọta miliọnu naira mii ti n o fi kun un yoo lọ sile awọn ọmọ alainiya."
Ọmọ baba olowo naa tun sọ pe oun ti gbe igbimọ kan dide ti yoo maa ri si bi wọn yoo ṣe pin owo ọhun.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla ti a wa yii ni Davido ke si awọn ọrẹ rẹ lori ayelujara pe ki wọn da miliọnu kọọkan naira fun oun lati fi ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi.
Ṣugbọn ka to wi, ka to fọ, awọn eeyan ti da owo to le ni ọgọrun un miliọnu naira jọ fun lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi naa laarin wakati mẹrinlelogun.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1992 ni wọn bi Davido.














