Olu Jacobs: Joke Silva sọ̀rọ̀ lórí ìlera ọkọ rẹ̀, ó ní ó ń bá àìsàn tó ń mú ni gbàgbé nǹkan ló ń ba jà

Oríṣun àwòrán, Instagram/@Joke Silva
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Joke Silva ti sọrọ soke lori ilera ọkọ rẹ, Olu Jacobs, ti oun naa jẹ agba oṣere.
Bo tilẹ jẹ pe o ti to ọdun melo kan ti Olu Jacobs ti kopa ninu ere tiata kẹyin, amọ o yọju sibi ayẹyẹ ere ori itage kan, Africa International Film Festival Awards, AFRIFF, to waye niluu Eko.
Nibẹ si ni ọpọ eeyan ti ri pe gbajumọ osere tiata naa ti ru pupọ, eyi to fihan pe aisan n yọ lẹnu, ti agba si ti de si.
Ninu ifọrowerọ pẹlu awọn akọroyin, Joke Silva sọ pe o ti to ọdun diẹ sẹyin ti Olu Jacobs ti n ba aisan to maa n mu ki eeyan gbagbe nnkan, Dementia, finra.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba Eko fi ẹ̀bùn ńlá tọrẹ fún ìyá ọmọ tó kú lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation l‘Ojota
- Mọ̀ nípa àìsàn tó ń mú kí irun pọ̀ lára obìnrin láì ṣe ọkùnrin
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- Àlàyé rèé lórí ohun tó fa ìkúnsínú nínú ẹgbẹ́ Ìlana Omo Oodua
- Ìrìn-àjò ìfẹ́ wa kò tíì bẹ̀rẹ̀ nígbà tí mó ní Lateef Adedimeji kìí ṣe ọ̀rẹ́kùnrin mi- Mo’Bimpe
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko rún alùpùpù 482 tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọlọ́kadà jégé-jégé
- Mo ti ṣetán láti pín ₦250m sí ilé àwọn ọmọ aláìníyàá káàkiri Naijiria - Davido
- Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha
Joke sọ pe "O ti n ba aisan Dementia finra lati nnkan bii diẹ meji sẹyin, aisan naa fara jọ aisan to maa n mu ki ara eeyan ma gbọn ( Parkinson), ọpọlọ lo si maa n doju kọ."
O fi kun pe "Igba akọkọ ree ti n o sọrọ nipa aisan ọkọ mi ni gbangba, ṣugbọn mo ti mọ tẹlẹ pe ọjọ kan naa ni mo maa sọrọ nipa rẹ."
Joke Silva tun sọrọ nipa bi oun ati awọn mọlẹbi rẹ ṣe n farada aisan Olu Jacobs.

Oríṣun àwòrán, AFP
O ni "Ko rọrun fun un nitori ko fi bẹẹ ni oye ohun to n ṣẹlẹ ati bo ṣe ri lara awọn mọlẹbi rẹ, ṣugbọn a fi ọpẹ fun Ọlọrun."
Agba oṣere naa fi kun pe lẹnu lọọlọ yii ni awọn ṣẹṣẹ la awọn ohun kan kọja, ti oun ko le maa sọ ni ojukaye.
Joke sọ pe "A ti la awọn nnkan kọja lẹnu ọjọ mẹta yii ṣugbọn a fi ọpẹ fun Ọlọrun fun anfani to fun wa lati le maa koju awọn ipenija naa, emi ati ọkọ mi n saaro awọn igba ti a ti dọjọ ṣiṣẹ papọ sẹyin."
Akoko kan ni awọn eeyan kan ti kọkọ n gbe iroyin kiri pe Olu Jacobs ti jade laye ṣugbọn awọn iroyin naa jẹ ofege ni igbẹyin gbẹyin.
Ẹwẹ, lẹyin ti fidio ayẹyẹ ọjọ Olu Jacobs jade si ori ayelujara ni ọpọ eeyan bẹrẹ si n woye irufẹ ipo ti agba oṣere naa wa nitori bo ṣe ru bi ẹni to n ṣaisan.
Wayi o, ibi ayẹyẹ ami ẹyẹ ere ori itage AFRIFF to waye niluu Eko ni wọn ti fun Olu Jacobs ni ami ẹyẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn agba ọjẹ ninu iṣẹ tiata to lamilaaka julọ ni Naijiria.
Lẹyin ti Joke pin aworan oun ati ọkọ rẹ lori ayelujara tan ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ bẹrẹ si n kii ku oriire fun ami ẹyẹ naa, ṣugbọn ọpọ awọn mii lo n beere pe, ṣe ko si nnkan nitori irisi rẹ jọ ti ẹni to n ṣaisan.


















