Okada ban: Iléeṣọẹ́ ọlapàá ìpínlẹ̀ Eko rún alùpùpù 482 jégé-jégé lẹ́yìn tí wọ́n gbẹ́sẹ̀le lọ́wọ́ àwọn ọlọ́kadà

Oríṣun àwòrán, ADEKUNLE AJISEBUTU
Ijọba ipinlẹ Eko ti run alupupu ti iye rẹ din diẹ ni ẹẹdẹgbẹta jege-jege lẹyin ti wọn gbẹsẹle awọn alupupu naa kaakiri ipinlẹ ọhun.
Awọn alupupu naa wa lara awọn ti wọn gba lọwọ awọn ọlọkada to tapa si ofin ijọba ipinlẹ naa pe oun ko fẹ ri awọn ọlọkada lawọn agbegbe kan.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, CSP Adekunle Ajisebutu fi lede lọjọ Abamẹta, o ni ileeṣẹ naa gba awọn alupupu ọhun kaakiri ipinlẹ naa.
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
- Bí ọmọbìnrin tí wọ́n parọ́ mọ́ pé ó gbé òògùn olóró tó sì wọ ẹ̀wọn ní Saudi ti dara pọ̀ mọ́ NDLEA
- Mo ti ṣetán láti pín ₦250m sí ilé àwọn ọmọ aláìníyàá káàkiri Naijiria - Davido
- Irú ikú wo gan ló pa àbúrò Dangote? Aliko Dangote ṣàlàyé àwọn ǹkan tó ṣẹlẹ̀ kí abúrò rẹ̀ tó kú
- Ó yẹ́ kí àwọn olóṣèlú kẹ́kọ̀ọ́ lára Goodluck Jonathan, olùfẹ́ ìrẹ́pọ̀ ni - Lawan
- Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha
- EndSARS Panel report: Amẹrika ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ìwàdìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn Lekki toll gate
- Buhari ní òun á gbé ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu yẹ̀wò
- Buhari buwọ́lu N656 bílíọ́nù owó ìdólà fún àwọn ìpínlẹ̀
Nigba to n sọrọ nibi ti wọn ti run awọn alupupu ọhun jege-jege ni ọọfisi ijọba to wa ni Alausa, kọmiṣọna ọlọpaa, Hakeem Odumosu sọ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn yoo run awọn alupupu ti wọn gbẹsẹle bẹẹ.
Odumosu ni wọn ti maa n run awọn ọkada jege-jege bẹẹ tẹlẹ, ṣugbọn awọn ni lati jẹ ki awọn araalu mọ ibi ti awọn alupupu ti awọn n gbẹsẹle n lọ lo jẹ ki wọn ṣe ni ojukaye.

Oríṣun àwòrán, ADEKUNLE AJISEBUTU
Kọmiọna naa ṣalaye pe ni ṣe ni awọn maa n run awọn alupupu naa tako ọrọ ti awọn eeyan kan n gbe kiri pe ni ṣe ni awọn maa n ta awọn alupupu ti wọn ba gbẹsẹle ni gbanjo.
Lẹyin naa lo kilọ fun awọn ọlọkada to n tapa si alakalẹ ijọba ipinlẹ Eko lori irinsi awọn ọlọkada lati so ewe agbejẹ mọwọ.
O ni ki awọn to n ṣe ọkada lawọn ibi ti wọn ti fofin de lọ yi iwa wọn pada, bi bẹẹ kọ, wọn yoo foju wina ofin laipẹ.
Odumosu tun sọ siwaju si pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa run awọn ọkada ti wọn ba gbẹsẹle jege-jege titi ti awọn to n tapa si ofin naa yoo fi yi iwa wọn pada.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2020 ni ijọba ipinlẹ Eko gbẹsẹle ọkada lawọn agbegbe kan nitori eto abo ati oniruru ijamba to maa n waye awọn agbegbe ọhun.














