Ọlọ́pàá dóòlà òṣìṣẹ́ iléèṣẹ́ 'Pure Water' méje tí ajínigbé gbé sálọ ní Kwara

Ọlọpa ilẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ̀ yòó wáyé

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti doola eeyan meje to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ kan to n ṣe omi inu ọra 'Pure water' lọwọ ajinigbe.

Ọjọ Ẹti ni iroyin sọ pe awọn agbebọn kan yawọ ileeṣẹ Lafrcdeen Pure Water to wa ni abule Sosoki, ti wọn si ji oṣiṣẹ meje ati ẹni to ni ileeṣẹ naa gbe lọ…

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Okasanmi sọ ninu atẹjade kan pe oṣiṣẹ kan pere ni ori ko yọ ninu ikọlu naa.

Yatọ si awọn eeyan yii, awọn agbekan naa tun ju ọkunrin agbẹ kan, Olulaja Adegboja, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta gbe, lasiko to n bọ lati oko rẹ ni Olla.

Okasanmi sọ pe gende ọkunrin mẹfa to ni nkan ija oloro lọwọ lo gbe ọkunrin na, ti wọn si gbe wọ inu igbo.

O ni "ni kete ti iroyin naa jade, ni kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ naa, CP Tuesday Assayomo, ko awọn ọlọpaa kogberegbe sita, ti wọn si ri awọn eeyan naa gba pada pẹlu ajọṣepọ awọn ọlọdẹ ati fijilante.

"Akitiyan wọn lo yọri si didoola meje lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Pure Water naa, ti wọn si n gbiyanju lati doola awọn to ku si ahamọ ajinigbe."