Kevin Strickland: Ẹni ogún ọdún ni mo wọ ẹ̀wọ̀n, wọn tú mi sílẹ̀ lẹ́ni ọdún 62 pé ń kò jẹ̀bí ẹ̀ṣẹ̀ náà

Kevin Strickland

Oríṣun àwòrán, Midwest Innicence Project

Arakunrin kan ti wọn fẹsun ipaniyan kan, ti wọn si ran lọ sẹwọn ọdun mejilelogoji, ti gba itusilẹ ti wọn si ni ko jẹbi ẹsun to gbe de ọgba ẹwọn naa.

Lati igba to ti wa ni ẹni ọdun mejidinlogun, ni wọn ti mu Kevin Strickland fun ẹsun ipaniyan amọ o n lọgun pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Sugbọn wọn papa sọ sẹwọn ni osu Kẹfa ọdun 1979, to si lo ọdun mejilelogoji gbako ni ahamọ ijọba naa.

Nigba ti wọn tu silẹ ni ita ile ẹjọ, n se lo sọ pe ''Mi o lero pe maa ri iru ọjọ oni''

Ninu iwe akọsilẹ nipa awọn eeyan to ri itusilẹ gba kuro lọgba ẹwọn, akoko ti Kevin Strickland lo nibẹ, lo jẹ igba to pẹ julọ ti eeyan kan lo lẹwọn lai jẹbi.

Amọ labẹ ofin Missouri lorilẹede Amẹrika, ko daju pe yoo ri owo gba ma binu kankan gba fun ẹjọ ẹbi ti wọn da fun naa.

Ninu akọsilẹ bakan naa, akoko ti Kevin Strickland lo ni itimọle lo tii pẹ julọ lati ọdun 1989 ati pe, ninu akọsilẹ orileede Amẹrika, oun lẹni keje to pẹ julọ lẹwọn lai jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Lọjọ Isẹgun ni adajọ sọ pe ki wọn tu Kevin Strickland pada.

Àkọlé fídíò, Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

Ki lo de ti wọn se ran Kevin Strickland ni ẹwọn?

Ọjọ Kẹẹdọgbọn osu kẹrin ọdun 1978 ni wọn ran Strickland lọ si ẹwọn aadọta ọdun, lẹyin tawọn kan digun jale ni ile kan to wa ni Kansas.

Lalẹ ọjọ taa n wi yi, awọn agbebọn mẹrin yinbọn pa eeyan mẹta ninu ile naa: Sherrie Black, ẹni ọdun 22, Larry Ingram, ẹni ọdun 22, ati John Walker, ẹni ọdun 20.

Eeyan kẹrin to moribọ, Cynthia Douglas ẹni ogun ọdun dibọn bi igba pe o ti ku.

Ọrẹkunrin ẹgbọn Cynthia lo sọ fawọn ọlọ́paa pe oun fura si arakunrin Strickland.

Ohun naa lo tun fokun mọ Cynthia lati naka si Strickland nigba ti awọn ọlọpaa se afihan awọn afurasi.

Arakunrin Strickland sọ fun awọn ọlọpaa pe ile loun wa nigba ti isẹlẹ yi waye.

Ko si ẹri kankan to fi han pe o kopa ninu iyinbọn paniyan yii .

Ọdun 1979 ni igbẹjọ rẹ alakọkọ pari, ti wọn ko si ribi fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi.

Igbẹjọ keji to sẹ pe awọn eeyan alawọ funfun nikan lo gbẹjọ rẹ sọ pe o jẹbi ẹsun ipaniyan.

Bawo ni Kevin Strickland se ri idajọ ododo gba?

Lẹyin ọdun meloo kan arabinrin Douglas to naka si pe o kopa ninu ipaniyan naa pada sọ́ pe ọrọ ko ri bẹẹ mọ.

''Ninu iwe to kọ si ajọ Midwest Innocence Project, o ni ''nnkan ko ye mi daadaa nigba naa sugbọn mo ti nimọ si bayii, maa si fẹ se iranwọ fun arakunrin yii lọnakọna''

O se ni laanu pe arabinrin Douglas jade laye ko to le jẹri nile ẹjọ lati yi ọrọ rẹ pada sugbọn iya rẹ ati ọmọ rẹ jẹri niwaju adajọ pe alaisẹ lẹni to jẹri pe o seku paniyan.

Losu kọkanla ọdun to kọja ni wọn se agbeyẹwo idajọ rẹ.

Labẹ ofin tuntun kan to wa ni Missouri, wọn kọwe si adajọ lati tu Strickland silẹ, ki wọn si sọ pe ko mọ si ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ James Welsh to gbe idajọ kalẹ lọjọ Isẹgun sọ pe ''ile ẹjọ ko ni igbagbọ ninu idajọ to ran Strikland lẹwọn tori naa o di dandan ki wọn wọgile''

Arabinrin Rojo Bushnell ti ajọ Midwest Innocence Project sọ pe, ilana yii fi han ''o lagbara gan lati se atunse asise labẹ ofin.

Agbẹjoro ijọba gba lootọ pe arakunrin Strickland ko jẹbi sugbọn ọpọ osu ni wọn lo, ki wọn to tu silẹ. Ko yẹ ko le to bayi''

Àkọlé fídíò, Ìṣẹ̀lẹ̀ Kàyéèfì: Ìpáǹle tú Abass Owonikoko sí ìhòòhò ayé, kó tó gba kéú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Se Kevin Strickland yoo ri owo "gba ma binu" gba bi fun bo se se ẹwọn laitọ?

Awọn agbẹjọro lati ẹka Midwest Innocence Project ti wọn gba ọrọ rẹ ro sọ fun BBC pe, n se ni inu awọn dun kọja aala nigba tawọn gbọ iroyin yii.

Adari eto idajọ Midwest Innocent Project Tricia Rojo Bushnell sọ ninu atẹjade pe ''A ni igbagbọ pe eyikeyi adajọ to ba ri ẹri ta gbe wa, yoo sọ pe arakunrin Strickland ko jẹbi, nkan to si sẹlẹ naa ree''

O tẹsiwaju pe ''ko si nkankan to le da ọdun mejilelogoji to ti lo lọgba ẹwọn pada ati pe ni ipinlẹ to ti sẹwọn yii, wọn ko ni san owo gba ma binu kankan fun. Eleyi kii se idajọ ododo''

Gẹgẹ bi ajọ yii ti sọ, ipinlẹ Missouri kii san owo gba ma binu fawọn ti wọn ran lẹwọn lalai jẹbi ayafi ti DNA ba fi han pe wọn ko jẹbi.

Koda ki awọn eeyan jẹ́ri pe wọn ko jẹbi, wọn o ni san owo gba ma binu fun wọn.