Akure Baby on the Altar: Wọ́n fi orúkọ aya Akeredolu sọ ọmọ tuntun tí wọ́n bá ní pẹpẹ ṣọ́ọ́ṣì

Ọmọ tuntun ti wọn gbe sori pẹpẹ atawọn ohun eelo rẹ lẹgbẹ rẹ

Ọmọ ti wọn gbe ju si ori pẹpẹ ile ijọsin Kerubu ati Serafu Holy Trinity ni opopona Ọda n'ilu Akure n'ipinlẹ Ondo ti ẹnikẹni ko mọ awọn obi rẹ lo ti bẹrẹ igbe aye tuntun n'ile awọn ọmọ alailobi t'ijọba ipinlẹ Ondo.

Ọmọ naa to jẹ ọmọbirin ni wọn ti sọ ni Betty Emmanuella Akeredolu, lẹyin tawọn oṣiṣe ile iṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n ri si ọrọ awọn obirin ati idagbasoke awujọ gba a s'ọdọ.

Adele akọwe agba ile isẹ naa, Arabirin Foluke Tunde-Daramola fi idaniloju han pe ọmọ naa ni yoo gba itọju to peye n'ile awọn ọmọ alailobi ti o wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa koro oju si bi awọn eeyan kan ṣe n gbe ọmọ sọnu lai ro ti irora oyun nini ati ti ọjọ ikunlẹ.

"Ọpọlọpọ ohun lo le ṣ'okunfa bi gbigbe ọmọ sọnu ṣe n peleke sii lawujọ.

"Itọju ọmọ ni kii ṣe ohun ti a le f'ọwọ yẹpẹrẹ mu, nitori naa ẹni ti ko ba tii ṣetan ni lati jina si ibalopọ tabi ki o daabo bo ara rẹ".

Àkọlé fídíò, Afeez Akintunde: Àwọn ẹbí Tula Oyo figbe tá pé kò ní ohunkohun ṣe pẹ̀lú Yoruba Nation

O ni bo tilẹ jẹ pe awọn oogun kan wa ninu ọra lẹgbẹ ọmọ naa lakoko ti wọn rii, ọmọ naa lo wa ni alaafia to si n ṣere rẹ lati igba to ti de ọdọ wọn.

Alukoro ileesẹ ọlọpa ni ipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami sọ fun BBC Yoruba pe, awọn ti bẹrẹ iwadi lati ṣawari iya ọmọ naa.

Amin iyasọtọ kan

Bawo ni wọn ṣe raaye gbe ọmọ naa sinu ṣọọṣi lasiko ti ilẹkun wa ni titi pa?

Ori pẹpẹ ti wọn gbe ọmọ tuntun si

Igbe haa, hee, ta lo ni ọmọ, ikunlẹ abiyamọ o, lo gba ẹnu awọn olugbe ilu Akure kan ni aarọ Ọjọru, nigba ti wọn sadede ri ọmọ tuntun jojolo kan ninu ile ijọsin Kerubu ati Serafu Holy Fountain.

Agbegbe Oda road, nilu Akure, tii se Olu-ilu Ipinle Ondo ni isẹlẹ naa ti waye ni aarọ ọjọ isẹgun.

Ẹjẹ ọrun naa ni ko le ju ọmọ ọsẹ kan lọ, ti wọn si fi asọ alawọ eweko kan we, ki wọn to gbe si ori pẹpẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oludasilẹ ijọ naa Biṣọbu John Ikoko, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bi isẹlẹ naa se waye ni oun ni oun ri ọmọ naa lẹyin toun gbọ igbe ọmọ tuntun latinu ile ijọsin, lẹyin adura owurọ ninu ile rẹ ti ko jinna si ile ijọsin naa.

Gẹgẹ bi ọrọ ikoko, kete ti ohun si ilẹkun ile ijọsin naa, ni oun ri ọmọ tuntun ni ori pẹpẹ (Altar), to n sunkun kikan kikan.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

O salaye pe pẹlu bi ọrọ se ri, o han gbangban wipe iya ọmọ naa ni yoo gbe ọmọ naa sibẹ nitori o ko awọn eroja kan sẹgbẹ ọmọtuntun ọhun.

Awọn eroja naa si lo jẹ awọn nnkan eelo bii aṣọ, oogun oyinbo, ati ike-ifọmọlounjẹ taa mọ si feeding bottle.

Ojisẹ Ọlọrun naa fikun pe, iya ọmọ naa lo seese ko gba ferese ile ijọsin naa wọle bi o ti je wipe titi pa pẹlu kọkọrọ ni ilẹkun ile ijọsin naa wa.

O sọ siwaju pe, ohun ran iyawo oun lọ si agọ ọlọpa to wa ni Ala lati fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.

Lẹyin wakati kan si akoko naa, awọn ọlọpa lati agọ ọlọpa to wa ni Ala de si ile-ijọsin naa, wọn si ti gbe ọmọ tuntun naa lọ.

Ọmọ tuntun ti wọn gbe sori pẹpẹ atawọn ohun eelo rẹ lẹgbẹ rẹ